Home ÀKỌ̀TUN Makinde kò tíì yí àṣẹ àfàró padà lórí i ẹgbẹ́ awakò NURTW ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Makinde kò tíì yí àṣẹ àfàró padà lórí i ẹgbẹ́ awakò NURTW ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Makinde kò tíì yí àṣẹ àfàró padà lórí i ẹgbẹ́ awakò NURTW ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹ ma fori ọka họmú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe ko ko ko bayii la a ranfa fẹni eti n yọ lẹnu,idi niyi ti Ijọba ipinlẹ Ọyọ fi soju abẹ niko pe ,ko sohun to yipada lori ofin to gbẹsẹ le iṣẹ awọn ẹgbẹ awakọ ero, NURTW ni ipinlẹ Ọyọ.
Ninu atẹjade kan ti ajọ amojuto lilọ-bibọ ọkọ nipinlẹ Ọyọ, OYRTMA fi sita ni ọrọ yii ti jẹyọ.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni awọn ti n gbọ finrinfinrin pe awọn eeyan kan ti n ṣe kurukẹrẹ kaakiri lọna ti ko bofinmu ti wọn si n pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ awakọ ero, NURTW nipinlẹ Ọyọ.

Arumọjẹ ti wọn si n ṣe fun awọn araalu atawọn awakọ ẹgbẹ wọn ni pe, aṣẹ ti ijọba fi gbe ẹsẹ le ẹgbẹ naa ti yọ bi ori inu oorun ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019.
Eleyii ti wọn ni o fun awọn lanfani lati tun bẹrẹ si nii da tabi gba garaaji atawọn ibudokọ gbogbo nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si fi n doju ija kọ awọn oṣiṣẹ ORTMA ati lati da omi alaafia ilu ru.

Ajọ OYRTMA nipinlẹ Ọyọ ko ṣai wa tẹnumọ pe titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ofin ijọba eleyii ti gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde pa ṣi wa sibẹ digbi o.
Wọn ni aṣẹ naa gẹgẹ bii alakoso agba fun eto aabo nipinlẹ Ọyọ ṣe pa,pe ki wọn gbẹsẹ le eegun ẹgbẹ awakọ ero pe ko gbọdọ ṣẹyọ bayii nipinlẹ naa ṣi wa ni sẹpẹ o ati pe , ẹnikẹni to ba fọwọ pa ida aṣẹ naa yoo fata gungun le tiro o ofin.

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni gomina Onimọ ẹrọ Ṣeyi Makinde ti wọn ṣẹṣẹ bura fun gori apere nigba naa paṣẹ pe eegun ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ naa ko gbọdọ ṣẹyọ mọ fun asiko yii.
Makinde sọrọ naa nitori rogbodiyan ti wọn fẹ maa da silẹ nigba naa nitori ati yii ijọba pada pẹlu ayipada to de ba ijọba nigba nipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…