Home ÀKỌ̀TUN O̩mo̩ ààlè Naijiria ló ń gbè lé̩yìn South Africa – Falana
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 6, 2019

O̩mo̩ ààlè Naijiria ló ń gbè lé̩yìn South Africa – Falana

O̩mo̩ ààlè Naijiria ló ń gbè lé̩yìn South Aftica

Agbejoro agba to maa n ja fun eto omoniyan, Alagba Femi Falana lo n ba awon oniroyin soro ni ilu Eko ni ana ode yii.
Falana ni iwa buruku gbaa ni awon omo orileede South Africa n wu nipa didana sun awon omo Naijiria.
O ni ase ni awon kan n so nipa sisalaye pe egbo igi oloro ati awon iwa ibaje to wo awon omo Naijiria lewu lo fa didana sun ti won n dana sun won.
Falana ni ko ye ki ijoba orileede naa faaye gba iru re nitori pe ile-ejo wa ni ilu naa. O ni o ye ki won je ki gbogbo agbaalaaye mo ese won pelu iru ijiya to to si won.
Falana ni elo ni awon Naijiria naa n pa ti won fi ni won gba ise mo awon lowo. O ni se won le se afiwe owo ti awon omo naa n pa pelu nnkan oro aje tiwon ni orileede Naijiria.
O ni nnkan buruku ni ki awon kan wa maa gbe iro pooyi enu pe awon omo buruku ni won n pa.
Alagba Femi Falana ni bi a se fi ote ati iwa eleyameya pelu elesimmesin ko wahala si orileede yii naa niyen. O ni iwa ajinigbe ko ba ma le gbile to bayii ti ki ba se iwa alaimokan ti a fi n pariwo awon Fulani darandaran.
O ni bi awon Yoruba se n jinigbe naa ni eya Igbo naa n se bee, o ni bee si ni awon eleya to ku.
Falana ro awon eniyan ki won maa wadii nnkan daju ki won to maa se idajo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…