Home ÀKỌ̀TUN Àwọn àgbà oyè ké̩yẹ pè̩lú Olubadan, lọ síbi ìpàdé ààbò …..
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 4, 2019

Àwọn àgbà oyè ké̩yẹ pè̩lú Olubadan, lọ síbi ìpàdé ààbò …..

Àwọn Agba Oye kẹyẹ pẹlu Olubadan, lọ sibi ipade aabo ……ẹ kọyin si gbọyi i sọyi ,idagbasoke ilu dọwọ ọ yin.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Awọn agba ni bi o ba tii rẹja, ọgbọn ohun imọ ati pẹtu si aawọ yoo kan maa sọ oloogun ti n wo abiku dalaimọọṣe ni

Idi ree ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi turaka fidunu ẹ han, to si ni ori oun wu pupọ lati ri awọn agba ijoye ilẹẹbadan ti wọn kọwọ rin pẹlu Olubadan ilẹ ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni.
Gomina Makinde, ẹni to woye ọrọ yii lasiko to n ṣide ipade apero lori eto aabo to waye nilu Ibadan lọjọ Aje,ko sai se sadankata si Olubadan ati awọn agba ijoye nilẹ Ibadan lori bi wọn se jẹ ki ogun sinmi, ti wọn si gba alaafia laaye.

Awọn agba ijoye naa, ti wọn tẹle owe Yoruba to ni ọba meji kii wa ni aafin, bi o tilẹ jẹ pe ijoye lee pe mẹfa laafin, ni wọn de fila lasan ati ilẹkẹ sọrun lai de ade sori, to si jẹ pe Olubadan nikan ni ade wa lori rẹ.

Ijoko Olubadan naa ati awọn ijoye rẹ to wu oju ri, to si jẹ pe oju gbogbo n wo wọn nibi ipade apero naa, lo mu ki gomina Makinde ni “inu mi dun lati ri awọn ijoye ti wọn kọwọ rin pẹlu Olubadan wa sibi.”
Ọrọ yii lo mu ki awọn eeyan bu sẹrin ayọ, ti wọn si patẹwọ, lati bu ọla funwọn,bẹẹ ni wọn n juwọ si ibi Olubadan ati awọn ijoye rẹ naa joko si.
Bẹẹ ba gbagbe , o ti to ọdun meji ti Olubadan ati awọn Agba ijoye nilẹ Ibadan ti dijọ jade sita gbangba papọ bayii, eyi ko si sẹyin wahala to waye nitori bi ijọba ana nipinlẹ Ọyọ labẹ iṣejọba Abiọla Ajimọbi ṣe de ade fun awọn agba ijoye mọkanlelogun nilẹ Ibadan.

Iwoye Iroyin ni pe awuyewuye laarin awọn agba ijoye yii ati Ọba Alayeluwa Soliu Akanmu Adetunji le damupitan,ti igun mejeeji ba le ja ka-in kan-in bọti, fọgbọn inu dẹyẹ sawọn oni gbọyi sọyi ẹda,ti wọn n pọnmi oke ru todo.

Lara awọn agba ijoye to kọwọrin pẹlu Olubadan ni Ọtun Olubadan, Agba Oye Lekan Balogun, Agba Oye Owolabi Ọlakulẹyin, Asipa Olubadan Eddy Oyewọle, Aṣipa Balogun Olubadan, agba Oye Lateef Adebimpe, Ẹkarun Olubadan, Agba Oye Amidu Ajibade ati Ẹkarun Balogun Olubadan, Agba Oye Kọla Adegbọla

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…