Home ÀKỌ̀TUN Seyi Makinde ṣe ìbúra fún kọmísánà tuntun mẹ́rìnlá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 16, 2019

Seyi Makinde ṣe ìbúra fún kọmísánà tuntun mẹ́rìnlá

Seyi Makinde ṣe ìbúra fún kọmísánà tuntun mẹ́rìnlá

Fẹmi Akinṣọla

Awọn agba bọ,wọn ni ọjọ lo n pẹ,ipade kii jina. Bẹẹ ba a dogun odun,dogbọn oṣu, o di dandan ki ọjọ ko.Asaọmọ yii lo dia fun bi Gomina Ipinlẹ Oyo,Onimọ Erọ Ṣeyi Makinde ti bura fawọn kọmiṣọna mẹrinla to ṣẹṣẹ yan l’Ọjọbọ nileeṣẹ ijọba l’Agodi niluubadan.
Baakan naa ni Gomina Makinde tun pin ileeṣẹ ti koowa a wọn o ti ṣiṣẹ ni kete to bura fun wọn tan.
Wọnyi ni awọn kọmiṣọna mẹrinla naa atawọn ileeṣẹ tẹnikọọkan wọn di mu gẹgẹ bi Gomina Ipinlẹ Oyo ti kede rẹ.

Amofin Adeniyi John Farinto ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ Eto Iṣuna ati aato.

Ọgbẹni Adeniyi Adebisi ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ to wa feto okoowo.

Ọgbẹni Muyiwa Jacob Ojekunle di kọmiṣọna fun eto ọgbin.

Ọjọgbọn Oyelowo Oyewo lo jẹ Kọmiṣọna fun eto idajọ.

Amofin Olasunkanmi Olaleye ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ idasilẹ.

Agbẹjọro Seun Asamu ni kọmiṣọna tuntun fun ileeṣẹ ohun amusagbara.

Ọgbẹni Rahman Abiodun AbdulRaheem ni kọmiṣọna fun ọrọ ilẹ.

Oloye Bayo Lawal ni Kọmiṣọna fun fawọn akanse isẹ.

Asofin Funmilayo Orisadeyi lo jẹ kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.

Dokita Bashir Bello lo jẹ kọmiṣọna fun eto ilera.

Họnarebu Wasiu Olatunbosun ni kọmiṣọna fun eto iroyin.

Ọjọgbọn Daud kehinde Sangodoyin ni Gomina ni o dileese eto ẹkọ mu giri.

Ọgbẹni Akinola Ojo ni kọmiṣọna tuntun fun eto inanwo nipinlẹ Oyo.

Asofin Kehinde Ayoola ni Gomina kede gẹgẹ bii alabojuto ọrọ ayika

Gomina ko sai rọ wọn ,lati ri iyansipoo wọn bii anfaani,lati sinu fundagbasoke,ki wọn si rii pe wọn nifarajin,la kaka, lati kọ itan rere,ti yoo se e ka ,fawọn iran to n bọ wa.
.
.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …