Home ÀKỌ̀TUN Gbogbo ẹ̀yin tí ipò kò tíì kàn, ẹ fọkàn balẹ̀, yóò kàn yín láìpẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 14, 2019

Gbogbo ẹ̀yin tí ipò kò tíì kàn, ẹ fọkàn balẹ̀, yóò kàn yín láìpẹ́

Gbogbo ẹ̀yin tí ipò kò tíì kàn, ẹ fọkàn balẹ̀, yóò kàn yín láìpẹ́

Femi Akinsola

Ọrọ okeere,bi o dinkan, a lekan,lo jẹ́ ki Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ Seyi Makinde o tun satẹnumọ rẹ pe, àwọn agbáṣésẹ abẹ́lé ní ìjọba òun yóò maa gbé iṣẹ́ kọ́ngila ìpínlẹ̀ Ọyọ fún, lójunà àti kópa tiwọn nínú ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀,ati pe ki àwọn to n reti i ipo kan tabi omiran o fọkanbalẹ̀.
Makinde fọ̀rọ̀ yìí léde làsìkò to ń bá àwọn eeyan ilu Ogbomosọ sọrọ nígbà tó lọ sàbẹ̀wò “ẹ ṣeun, mo dupẹ” si wọ́n ní ìlú náà, fun atilẹyin ti wọn se fun lasiko eto idibo gomina to kọja.

O ní àwọn kọgila tó dáńtọ́ tí wọ́n sì mọ iṣẹ́ wọ́n bi iṣẹ́ tí akọsílẹ̀ sì ti fi hàn pé wọ́n kìí fi iṣẹ́ wọ́n ṣere ni àwọn yóò kọ́kọ́ gbé iṣẹ́ fún ní kété ti ìjọba bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òde.
Gómìnà ní ìjọba ò ti gbé iṣẹ́ kankan jáde láti ìgbà ti o ti dé, àti pé kí àwọn ara ilú lọ mú ọkàn wọ́n kúrò nibi pé bóya àwọn ti gbé iṣẹ́ fún àwọn ará ìta.

Dípò o bẹ́ẹ̀ “a ó gbé iṣẹ́ fún kọngilá tó jẹ ará ìlú láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀rọ̀ ajé ìpiínlẹ̀ Ọyọ àti láti jẹ́ kí wọ́n ni ipa nínú ìjọba”
O rọ gbogbo àwọn ti wọ́n ń retí ìpò kàn tàbí òmíràn nínú ìjọba rẹ̀ láti lọ fí ọkàn balẹ̀ nítorií yóò kàn wọ́n láìpẹ́.

Bakan naa lo tun rọ awọn araalu pe eto idẹrun wọn lo ṣe pataki julọ si ijọba oun, ati pe, oun seleri saaju idibo pe, oun yoo tukọ ipinlẹ Ọyọ pẹlu ibẹru Ọlọrun,o ni ori ipinu naa ni oun si wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …