Home orisiirisii Plateau stories: wón ti wú òkú ìyá lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n sin ín.
orisiirisii - Orisirisi - August 6, 2019

Plateau stories: wón ti wú òkú ìyá lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n sin ín.

 

Won ti wu oku iya odun mesanlelogorun leyin ijo meji ti won sin in, eyi waye leyin ti won ri pe molebi miiran lo sesi sin oku iya naa ni Jos, ipinle Plateau.

Arabinrin Naomi Bot ku ni july 26, 2019, won si fe sin in ni ojo Monday August 5, 2019 ni Assemblies of God Church, ni ilu Danye Turu ni Jos South Local Government Area ni ipinle Plateau.

Amo won sesi sin in ni ojo Satide, August 3, 2019 ni ipo Arabinrin Kumbo Pam Badung, omo odun metalelogorun.

Mrs Badung ku ni July 24, 2019, won si fe sin in si egbe COCIN LCC Rawuk, Vwang ni Jos South LGA. Amo won fi oku re sile si Vom Christian Hospital Motuary, nibi ti won gbe oku Mrs Bot si.

Ni aaro ojo Monday ti awon molebi Mrs Bot lo si motuari ni won ri nnkan to sele.

Awon molebi, ore ati ara ti n duro ki won sin iya naa, ki okan lara awon molebi re to ni oun fe wo iya naa ni ekan si ki won to sin in.

Nigba ti won si posi naa ni won ri pe kii se iya awon lo wa ninu re, won si kepe awon eeyan.

Nigba ti won se iwadii ni won ri pe won ti sesi gbe oku iya naa fun molebi miiran won si ti sin iya naa ni ojo meji seyin. Awon molebi si fariga pe ki won wu oku iya awon pe awon fe sin in funra awon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…