Home orisiirisii Kidnapped: Àwọn ọlọ́pàá Ghana ti mú àwọn omo Nigeria.
orisiirisii - Orisirisi - August 6, 2019

Kidnapped: Àwọn ọlọ́pàá Ghana ti mú àwọn omo Nigeria.

 

Awon olopaa orile-ede Ghana ti mu awon omo Naijiria mejila, leyin ti won mu arabinrin omo ogun odun ni idogo.

Won mu awon ti won fura si leyin ti baba arabinrin naa lo si ago olopaa lati lo kero pe oun ko ri omo oun obinrin. Gege bi iroyin se so, gbogbo awon ti won fura si naa jo n gbe ni ibi kan naa ni Weija STC.

Oruko awon ti won fura si ti awon olopaa fi kale naa ni Ose Winner, Oladide Ola Promise, Algbe Joseph, Edogiawerie Aisosa, Osazee Benjamin, Elis Imasuen, Emmanuel Daniel, John Miracle, Emulankpa Godwin, Osaro Kelvin, Oso Kenny ati Oghneyerhowa Nelson.

Arabinrin naa ni okan lara won fi ipa ba oun lo, oun si ni eni ti o tan oun wa, oun pade re lori afefe, o si ki oun gba ki o le gba oun ni alejo, amo nigba ti oun de ibe won o je ki oun jade mo.

Iwadii fi han pe awon mejila naa o ni iwe igbeelu, bee ni won n se jibiti ori afefe. Won ma fi oju ba ile ejo lonii Tuesday 6, August.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…