Home ÀKỌ̀TUN Rògbòdìyàn e̩gbé̩ awakò̩ Ìbàdàn, èsù sì ń tapo sí i
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 30, 2019

Rògbòdìyàn e̩gbé̩ awakò̩ Ìbàdàn, èsù sì ń tapo sí i

Fẹmi Akinṣọla

Awọn olugbe agbegbe Ẹgbẹda nilu Ibadan ti ṣe alaye wi pe igbiyanju awọn alakoso ẹgbẹ awakọ NURTW ipinlẹ Ọyọ lati wa ojutu si ofin ti ijọba fi de wọn lo ṣokunfa rogbodiyan ti o waye ni agbegbe naa lopin ọsẹ.lroyin owuro rii gbọ pe, ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ naa, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọlọpọ eeyan mọ si ‘Auxiliary’ lo ko awọn ọmọ ẹgbẹ kan lẹhin lati tọpinpin aṣoju igun mii ninu ẹgbẹ naa, ti wọn pe inagijẹ rẹ ni ‘Ajanaku’ wa si ile rẹ to n bẹ l’agbegbe naa.
Koko nnkan ti o ṣe okunfa ede aiyede lasiko abẹwo naa ko han si ẹnikẹni, eyii lo si mu ibẹrubojo de ba awọn olugbe adugbo naa, paapaa julo lasiko ti wọn ṣe akiyesi wi pe wọn fi ipa gbe ‘Ajanaku’ lọ si ile itura ‘Auxiliary’ to n bẹ ni agbegbe Alakia nilu Ibadan, gẹgẹ bi awọn aladugbo ṣe sọ.Wọn fi idi ọrọ mulẹ wi pe lẹhin wakati diẹ ni Ajanaku pada si ile rẹ ni agbegbe naa. Wọn ni Auxiliary ko ko ohun ija wa, bẹẹ si ni wọn ko yinbọn ni asiko abẹwo naa, ṣugbọn ifarahan wọn lo mu ki awọn olugbe Ẹgbẹda sa kijokijo lasiko naa.Bi o tilẹ jẹ pe olu ileeṣẹ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe alaye wi pe ahesọ ọrọ lasan ni wi pe iro ibọn ati awọn ohun ijagun oloro ni awọn ẹgbẹ awakọ fi le awọn olugbe Ẹgbẹda lopin ọsẹ ti a lo tan yii, ẹni ọrọ gberu papa a o kunu rara lori ọrọ naa

Nigba to n fesi lori ẹsun naa, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọgọọrọ eeyan mọ si ‘Auxiliary’ ṣalaye pe igbiyanju lati ba oun lorukọ jẹ ni iroyin ẹlẹjẹ naa.O tẹsiwaju wi pe awọn ọta itẹsiwaju ti n lepa lati mu ki oun padanu oju rere gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni eyi .Bi a o ba gbagbe a o rii pe, ko ju ọjọ diẹ ti wọn bura wọle fun Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ lo fofin de awọn ẹgbẹ awakọ, ti o si paṣẹ pe eegun wọn o tun gbọdọ ṣẹ ni gbogbo ibudokọ ati awọn ikorita ti wọn ti n gba owo,latari i laasigbo gbogbo igba,ti o mu pakaleke lọwọ,nigba naa lohun.Kete tigbeṣẹ yii waye lọga agba ẹgbẹ awakọ, labẹ aburada NURTW, Alhaji Najeem Usman-Yasin ti ba gomina ipinlẹ Ọyọ ṣe ipade bonkẹlẹ lori ọrọ naa, ṣugbọn ti ko jọ pefa fọre di asiko yii, tori aṣẹ naa ṣi duro digbi.Ṣe yooba bọ,wọn logun ti yoo wọle koni,ọna la tii pade ẹ.O jọ pe n lo mu ki gomina o yara paṣẹ nigba naa pe o to gẹẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…