Home ÀKỌ̀TUN Ara kò rokùn…
ÀKỌ̀TUN - ÀRÒJINLẸ̀ - July 24, 2019

Ara kò rokùn…

Eyin alarojinle, e ma ku ojo meta. Ilu lilu toni o ki n se ilu alujo rara. Eto aabo Orileede yii ni o n ko gbogbo wa lominu.
Eni to ba si ni oro naa ko kan oun, boya lo mo pe, nigba to kan oun tan, o tun se iwo mo o lara.
Awon ajinigbe ko kuku fi gbogbo igba maa gbe olowo, awon kan tile wa to je bii ojo ni won se n sise won, “ojo ti ko benikan ja, ti ko benikan re, to je wi pe eni ti eji ba ri ni eji n pa”.
Omowe kan ni won ji gbe fun ojo mefa ni opopona Ibadan si Ife. Baba yii lo salaye oun ti oju re ri lowo won. O ni oun ko je tabi mu fun ojo mefa naa. O ni afi igba ti ebi ati ara pelu ojulumo sa gbogbo ile jo ki oun to bo ni igbekun naa.
Baba yii ni ki a ma se foju Fulani darandaran nikan wo oro naa. O ni awon ara abule ti won n lo lo ti gbabode. Baba yii ni oun gbo ede Yoruba lenu awon ti won jo n duna dura ninu igbo naa. O ni pipa ni won n pa awon ti won ba jigbe ti won ko rowo gba lowo won.
Baba yii ni awon kan maa n gbe moto wa loru lati wa ra eya ara eniyan. O ni won maa n pa eniyan loju awon nitori pe emi ko jo won loju rara. O salaye bi won se n je isu, je agbado ninu oko naa ni eyi to tumo si wi pe asepo to dan mora wa laarin awon onise ibi yii ati awon ara adugbo naa.
Bi o se n sele ni ile Yoruba ni o n sele ni ile Hausa. Ju gbogbo re lo, okoowo awon eniyan buruku yii ti gbooro gan an. Ojo buruku esu gbomi mu ti won pa arabinrin aya Orekunrin to je omo Alagba Reuben Fasoranti naa ni won pa aburo baba Seneto Elisha Abbo ti won si tun ji okan ninu iyawo baba re gbe.
Bakan ni oro ologbon n ri, ti omugo nikan lo maa n yato. Alagba Olusegun Obasanjo ati ojogbon Wole Soyinka naa je ki o ye gbogbo wa pe oro naa ti koja ohun ti a maa n fi oro oselu tabi eya yanju.
Bi oro se ri bayii, awon odo wa ko fe ise se mo, owo ofe nikan ni won fe. Eyi maa mu ki onikaluku san sokoto re daadaa. Ki a koko bere lati inu ile wa, ki a funra de adugbo ati ilu kookan. Ti o ba seese ki olopaa ibile ati ipinle bere.
Bi oro naa se ri bayii, “ara ko ro okun, bee naa si ni ara ko ro adiye”. Eni to lowo ko le rin falafala bee si ni talaka ko fe ki won pa oun rubo. Gege bi imoran temi, ki ijoba apapo je ki a pa egbe, eya ati esin ti segbe kan ki a wa gbaju mo isoro orileede yii. Eyi nikan naa lo le je ki a bori isoro naa.
O tun di osu to n bo lase Edumare. Ire o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…