Home iroyin Àìláábò: Alaafin kọ ìwé-ẹ̀dùn sí Ààrẹ Buhari.

Àìláábò: Alaafin kọ ìwé-ẹ̀dùn sí Ààrẹ Buhari.

Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi III, ti ko iwe edun si Aare Muhammadu Buhari nipa ipa odi ti aini aabo ni si Naijiria, paapaa ni Gusu Ila-Oorun, o si n kilo pe ilana ijoba asaaju o ti i wo patapata ni ile Yoruba.

O so pe opolopo orile ede ni won ti fi ofin ti ko ni gba awon omo Naijiria laaye lati wo ilu won, o si n kilo pe igba die lo ku fun Naijiria lati padanu ipo re ninu apejopo eto agbaye.

Oba naa si gba Buhari ni imoran pe ki o gbe igbese ti yoo fi ifokanbale si ijoba re ati lati fi ipa awon ipinle han bi won se le daabo awon nnkan to wuni.

Leta naa ti won deeti ni ojo ketadinlogbon, osu kefa odun 2019, bo sita ni ana, eyi to je ojo die si igba ti leta ti aare ana, Oloye Olusegun Obasanjo ko tire nipa akole kan naa, bo si gbangba.

Leta naa ni:

‘Ibeere Yoruba ninu wahala Naijiria’, Alaafin toka si awon wahala metadinlogun ti n deruba Naijiria ti o si le fa wahala ti won ko ba se ayewo ti o peye lai se oju meji.

Oba Adeyemi so pe oju ko ti oun ri lati fi atileyin han fun aseyori ijoba Buhari lati gbe orile-ede naa lo si ile ileri rẹ, lati igba ti o ti gori ipo ni osu kaarun, ojo ketadinlogbon odun 2015.

Gege bi o se so, ifokanbale re ti ma n wa lori “ipa, amodaju ati agbara Buhari lati dari orile-ede naa lo li si ile ileri nibi ti ofin ati ilana ma bori, ominira awon eeyan ma a daju, igbesi aye to rorun ni awujo si ma wa fun mekunu.”

O so pe ifokanbale oun ninu Buhari o ye. Amo sibe, lenu ojo meta yii, okan mi o bale nipa oro abo ni orile-ede naa, paapaa ni Gusu Ila-Oorun, awon ile ti n so ede Yoruba, Kwara, Kogi ati Ipinle Edo.

“Eyi ni se pelu iwa ibaje awon Fulani ti n sin maluu ti won ti de panpe si gbogbo titi ti o lo si awon ile Yoruba. Yala ni Owo, Akure, Ilesa/Ife-Ibadan tabi agbegbe Ibarapa ati Ijebu ni ipinle Ogun, bakan naa ni o se ri ni gbobbo awon ile Yoruba.

“Mo ti se opolopo ipade pelu awon onimo ati awon olori Yoruba kaakiri nipa iwa ibaje awon Fulani ti n sin maluu pelu awon esun fi won fi kan won bii ifipabalopo pelu awon obinrin ati nigba miiran ni isoju awon oko won. Ti o si yato si bi won se n ba awon ile ogbin wa je; ti yoo si fa ebi ti won ko ba dekun re.

“Ey ti o bori re ni ti awon ajinigbe ti n wo aso awon ologun. Eyi ti n dani lokan ru ju ni ti ijiya ti ko si fun awon oni ise ibi yii, ti won si n fi igbadun se awon ise ibi won wonyi.

Leyin ipade pelu awon olori Yoruba ati awon ijoba isaaju ile Yoruba, okan wa daru nipa igboya ti awon eniyan yii ni lati ma hu awon iwa wonyii loju momo ni oju awon ona wa laisi awon oludaabo lati dekun re.

Eyi ti o tu buru ju ni igboya ti won ni lati maa bere owo emi, ti won si n gba ni awon ibi ti o wun won ti ko si si awon oludaabo ti won le mu won gege bi won ti n se seyin.

“Ni bayii, a ko le soro nipa iwode(parade) awon ti won fura si nitori ofin o ti i mu enikeni ni apa orile ede yii. Lai je pe ofin mu won, o ko le soro nipa pe ki won fi oju ba ejo.

O se ni laanu, o si dunni pelu, pe laaarin aisi abo lati odo awon igbimo idaabo, ibo ni a n lo?

“Eyi lo fa a ti o je pe awon eeyan wa, bi o tile je pe agidi ni won fi n se e, ti won fi n wa ana miiran lati daabo emi ati awon ohun ini won.

O to lati so pe, ni opo ile Yoruba, ilana ijoba asaaju o ti i wo patapata. Bi i, Egbe Oodua, Agbekoya ati awon egbe figilante miiran.

“Leyin gbogbo nnkan ti mo so soke, ati leyin ti mo ti fi ipo mi han ninu ijoba yin, ti o je pe gbogbo wa la gbagbo ninu ise akanse Naijiria, e jowo e fun mi ni aaye, Ogbeni Aare, lati so awon koko yii gege bi Alaafin Oyo, Oba ati Olori awon Yoruba n’ile ati l’oko ati Oloye Asoju asa ati ise Yoruba.

“Awon eeyan ni ipinle ibile mefefa ti agbegbe Gusu Ila-Oorun ti o tan de awon apa kan ni Kogi, Kwara ati Edo n gbe ninu iberu nitori aisi aabo fun emi ati ohun ini ti won n ri lojoojumo ti o si s’ajeji si won. Idagbasoke tuntun yii fi ara pe awon iwa odaran bii ọlọsa, ole jija ati ni enu ojo meta yii ajinigbe ati ifipabalopo awon mekunu ti ko m’owo m’ese, ti won si n pa ofin mo.

Mo ranti igba ti a koko sakiyesi awon isele yii ni agbegbe Oyo/Oke Ogun ni ipinle Oyo, mo gbe igbese lati fi alaafia si aarin awon agbe ati awon ti n sin maluu. Igbese wa ni aseyori nitori awon agbe ati awon ti n sin maalu tooto ni a n ba dowo po ti won si ni ero Naijiria lokan lati se igbega fun isele awujo ninu Naijiria ti o ni alaafia, aseyori ati isokan.

“Amo, o ti n di mimo pe iwa olosa ati ajinigbe ti ode oni ti yato si bi o se wa tele.

Lonii, kii se fun karakata lasan, amo fun ibaje ofin eto si aye ati ominira awon mekunu ile Yoruba. Awon apeere ti ko si ni gbangba kookan yoo foju han.

“Won ji awon eeyan kan gbe ni titi Erio-Aramoko ni ipinle Ekiti. Won fi iya je won, won si fi emi won w’ewu fun odindin ose meji.

Awon ti isele naa palara ni Akowe Nigerian Bar Association, ti Eka Ikole, Adeola Adebayo, ti won pada ri oku re ti n jera leyin ti won san milionu naira merin, owo ti awon ajinigbe naa bere fun.

“Won ji awon osise Federal Road Safety Corps meji gbe ni titi Ilesa-Akure, Yoruba si ni won. Inu isele naa ni okan ninu won ku si.

“Musibau Adetumbi, osise ofin ti n gbe ni Ibadan n lo si Ile-ejo Ebe(court of apoeal) fun ipade ni Akure nigba ti won ji gbe ni titi Ilesa-Akure. Won ji Ojogbon Adegbehingbe gbe, onise abe ni Obafemi Awolowo Yunifasiti, Ile-Ife ni titi Ibadan-Ile-Ife. Dr Muslim Omoleke, Akowe National Electoral Commission, won jigbe ni Ilesa, ipinle Osun.

Ogbeni Ayo Oladele, osise Guiness Nigeria ti o je akekoo ojo pipe ni Christ School, Ado-Ekiti, won ji gbe lo ni enu ojo meta yii. Dayo Adewole, omo okan lara awon egbe igbimo alase 2015-2019 ati minisita fun ilera, Ojogbon Isaac Adewole ni won jigbe ni oko re ni Iroko, ilu kan ni titi Ibadan-Oyo.

“ Bi awon isele oke yii se burewa to, awon omo ile Yoruba si wa ni alaafia, won o si hu iwa ti o ma lodi si ofin tabi lati lo awon nnkan ti won le fi daabo ara won ni ile won.

Won ti fi ifokanbale ninu yin han lati dekun awon isele odaran yii. Yoruba ti ko lati gbagbo ninu ero Islam tabi Fulani tuntun yii.

“ Wayi o, mo n ko iwe si i yin, gege bi eni ti o ni ipo ninu ijoba yin, lati pe akiyesi ati lati se apejuwe si i yin, idi ti o ye ki e le tete ko ibi ara si awon isele wonyi ati omiran ni ile Yoruba.

O ni ero kan nipa yin laaarin awon ti n tako yin pe, e ki i tara, ki e si gbe igbese to ye nípa oro ti o nise pelu orile-ede ati pe oro nipa aabo ni ile Yoruba kii da yin lokan ru.

“ E je ki n so abajade iwadii ti mo se ni ile Yoruba fun un yin, yato si akosile ti awon oludaabo yoo pese fun un yin, o ni imolara ti n wu nipa ipinlemi, ijakule, ati isoretinu laaarin awon eeyan wa, ti o si je pe ti won ko ba se ayewo nipa re, yoo fa wahala ti o le ati idaabo ni orile-ede.

Aini idaabobo n fa wahala ninu ise awon eeyan ninu isele awujo. Ewu ati wahala ti n se posi loju awon ona ati oko wa ni ile Yoruba n je ki oko dida ati awon ise awujo miiran bani leru.

Mo ranti pelu ibanuje pe Aafin Oyo atijo daru nitori oko eru fa aini idaabobo ti o si fa ki awon egbe ti n gbe Oyo leyin pada. Ko wun mi ki apa kankan ni Naijiria ri iru isele bayii mo.

“Yato si iparun oko ati awon ohun ogbin ori re, ilana awon Fulani tuntun, ti won n dibo bi i awon ti n sin maluu ti fi iberu si ile Yoruba.

Won ba nnkan ogbin je, won n ji okunrin ati obinrin gbe, won n fi ipa ba awon obinrin lopo, ni isoju awon oko won. Eyi fi han pe iyato gedegbe wa pe, kii se ija awon agbe ati awon ti n sin maluu, sugbon won n mo-on-mo hu awon iwa odaran yii ni.

Eyi ti o je ki o runi lokan ju ni pe, fun idi ti o je mimo ju fun awon olopaa, won o mu awon eni ibi yii tabi dibo pe won n daabo awon eeyan.

Ikundun(tendency) wa pe won a da awon ti isele naa se si lebi ati pe won yoo fi aini iranlowo han nipa mumu awon eni ibi yii lati fi oju ba ejo.

“Won ti e so, Ogbeni Aare pe awon odaran ti n sin maluu yii ma n hu iwa ibi yii loju momo ati lopo igba pelu aso ologun. Won n gbe ohun elo ijagun orisirisi, ti o je pe awon osere ipinle ni o ma n wa fun.

“ Ko si iyemeji pe idaabobo orile-ede yii ti di afagun.

Ero ati daabobo emi, ohun ini ati igbesi aye ti o rorun ni Naijiria ti sonu nipa idaabobo. Ni ile Yoruba, eru n ba wa nipa igboya ti awon odaran yii ni lati hu iru iwa yii ti awon oludaabobo o si ba won wi.

Ninu isele ti o je pe owo n ti owo d’owo, awon olopaa ni ohun elo lati se ayewo gbogbo owo ti Central Bank of Nigeria n gbe sita. Ki awon igbimo ti won ni imo je asaaju, ni ikaadi si awon odaran nigba ti o je pe won a na owo ti won ba gba nidii ise ibi won naa.

“Ni iwon igba ti o je pe ofin o tii mu awon Fulani ti n sin maalu kookan, won ko le gbe awon ti won fura si iwode tabi ile ejo.

Won n deruba olori ibile, won si n pase fun bi eni pe won koja ofin ati pe ofin o si le mu won. Ko se e gbo seti pe ipinle o le se iranlowo laaarin awon isele odaran wonyii, lati se ise to se pataki ju, idaabobo emi ati ohun ini.

“Ogbeni Aare, e je ki n so fun yin pe awa Yoruba ni ohun ibile ti a le fi daabobo ara wa lowo awon ota. Eyi ti o se koko ni aye lati lo awon ohun ibile yii lati daabobo ara wa boya ko ni lodi si ofin.

Mo mo pe awon omo egbe Oodua kaakiri agbaaye ti setan lati daabobo ile won, won ti setan lati da igbimo ologun ofe sile gege bi Agbekoya se se ni odun 1968.

“A le so pe eni ba yara logun n gbe. Ni temi, ati ti n ba tele oro ogbon, iponju ati idamu ti awon apase si se e tunse.

Ninu itan, ati ni oni, ibasepo eya Yoruba ati Fulani ti wa ni alaafia nipase awon olori ati oro iselu laaarin awon eya. Mo ti ni awon isele pupo nibi ti mo ti n yanju aawo laarin awon agbe ati awon ti n sin maluu ni aafin mi debi pe mo fi ilana sile fun ibasepo alaafia.

Nnkan ti o sejeji ni ero iwa odaran tuntun to wa laaarin awon eya Fulani. Nnkan ti o tun je ijakule ni pe, bi awon odaran yii se n kuro ni orile-ede wa pelu irorun, se ki iwa rudurudu wa ni ile wa.

Won ni ibomiran ti won le lo, amo awon omo Naijiria o ni ile imii yato si ibi.

“Eyi je isele pajawiro ni orile-ede, nigba ti awon Fulani ti n sin maluu n wu awon iwa odaran yii kaakiri orile-ede ti ijoba o si le se nnkankan nipa idaabobo. Ko si iyemeji pe awon olori kookan o to ise won se tabi won ko ni imo mo. Amo miiran gan o mo iru igbese ti o ye ki won gbe nipa oro odaran.

Nnkan ti o n sele ni Naijiria ki i se oju lasan, nitori ki i se nnkan ti o ye nibi ti oju la de yii, nigba ti gbogbo aye n ni ilosiwaju nipa igbesi aye ni awujo, awon omo Naijiria n gbe ninu iberu, olosa, egbe ole, ifipabalopo, ajinigbe ati ipanilaya.

“Aini idaabobo ti fa iberu nipa gbigbe ni Naijiria. O ni ipa lati ja orile-ede l’ole, o o fi han bi ailaju tabi oniyankeyan(barbaric).

“Bi opolopo orile ede se n fi ofin ti ko gba awon omo Naijiria laaye lati wo ilu won lele, igba die lo ku fun Naijiria lati padanu ipo re ninu ipade gbogbo agbaaye.

Mo gbagbo pe e o ni gba ki iru eyi sele, e si ma tete gbe awon igbese ti yoo fi ni lokan bale ninu ijoba yin, e si ma fi han pe ipinle naa ni ipa lati daabobo awon nnkan to wuni.

“Mo lero pe olorun yoo to o yin sona, fun yin ni igboya ati imo lati se nnkan to tọ, ati ti o ye lati ko Naijiria ti o wun wa, nibi ti won ko ni re eya kankan je tabi ro won si egbe.

“Bi mo se n ro yin lati ka akosile yii ati lati ri i pe o n bo lati odo okan lara ijoba yin, mo fi ikinni lati ipo olola daayin loju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…