Home ÀKỌ̀TUN Ayefe̩le̩ di bàbá è̩ta òkò
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 18, 2019

Ayefe̩le̩ di bàbá è̩ta òkò

Yinka Ayefele di bàbá eta oko

Femi Akinsola

Se awon agba bo won ninu eni kii dun ka pa a mora, eyi lo bi bi gbajugbaja olorin n ni, Yinka Joel Ayefele se senu foro, ṣalaye fawọn oṣiṣẹ rẹ lori eto kan to se lorii redio re,”let’s talk about it” ajoro.
Gbajugbaja olorin ni to tun jẹ oludaleeṣẹ redio silẹ, O ti kuro ni aheso bayii,pe Yinka Ayefẹlẹ ti di baba ibẹta gege bii iroyin iroyin owuro se gbo o,bi awada tosi di ooto.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe laipẹ yi ni iroyin kan ti kọkọ jade pe iyawo onkọrin yii bimo, ṣugbọn ti oun pẹlu tete bọ si igboro lati salaye pe iyawo oun ko tii bimọ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ rẹ to ba to ba iroyin owuro sọrọ ṣalaye pe ori oju opo ikansiraẹni Whatsapp to jẹ tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Redio rẹ lo ti tu iroyin agbodunu naa fun awọn oṣiṣẹ rẹ lonii.

Bakan naa ni Yinka Ayefẹlẹ funrarẹ ti kede rẹ loju opo Facebook rẹ pe orin ijo ọmọ mo ji fowurọ mi jo ti oun kọ ninu awo orin oun kan lọjọ ọjọsi ti di otitọ bayii,bi baba ibeta naa ti n yo sinkin lori eto to se lorii redio re Fresh FM nirole Tuside ni lbadan( 16/7/19,)pelu enikeji re lori eto Enitan Olusegun Bamidele,to opo eeyan mo si “EOB”
Iroyin owuro dawoo idunu pelu baba ibeta pe awon Omo naa yoo yan ,won o yanju loju emi obii won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Èèyàn méje kú n’Íbèṣè, nígbà táwọn ọlókadà kọjú ìjà síra wọn.

Èèyàn méje kú n’Íbèṣè, nígbà táwọn ọlókadà kọjú ìjà síra wọn. Ọrẹ Òtítọ́jù Ṣé wọ́n ní ìjàn…