Home iroyin Wọ́n ti mú àwọn márùn-ún tí wón lọ́wọ́ sí ikú olamide.
iroyin - July 15, 2019

Wọ́n ti mú àwọn márùn-ún tí wón lọ́wọ́ sí ikú olamide.

Awon olopaa ipinle Eko ti mu okunrun márùn-ún ati obinrin kan ti won lero pe won lowo si omo odun mejilelogun, Olamide Omolegbe, ti won fi esun iro kan pe o ji foonu.

Ni July 8, arabinrin kan ti n je Bolanle Muhammed fi esun kan Olamide pe o ji foonu ninu soobu oun, o si pariwo ole mo o, ariwo to pa ni o mu ki awon arakunrin kan naa Olamide titi emi fi bo lara re, ti won so ju oku re sinu osa ni Badore, Ajah.

Leyin ti won se eyi tan, ni omo arabinrin naa mu foonu naa wa pe oun ni owo mu, amo aso o bomoye mo, omoye ti rin wowo woja. Won ti gbemi eni ti ko se.

Awon olopaa ipinle Eki ti mu awon márùn-ún ti won lero pe won lowo ninu iku omo naa, awon si ni Wasiu Wahab, Ramon Ibrahim, Junior Adebayo ati Yusuf Adegbite.

Awon mererin ni won naa ti won si ju oku re sinu osa, ki awon olopaa to ri oku re ni ojo Wednesday July 10 ti won si gbe lo si motuari.

Won i mu awon okunrin mererin ati arabinrin ti o fi esun iro kan oloogbe naa. Won si ti jewo ese won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…