Home iroyin Ọkọ ti fi àdá ṣa iyawo rẹ̀ nítorí àgbèrè.
iroyin - orisiirisii - Orisirisi - July 13, 2019

Ọkọ ti fi àdá ṣa iyawo rẹ̀ nítorí àgbèrè.

Awon olopaa agbegbe Bugweri, Uganda ti n wa arakunrin kan ti o fi ada sa iyawo re leyin ti o fi esun kan an pe o n se isina.

Isele naa waye ni ojo Wednesday ni ilu Butende ni Ibulanku Sub County nibi ti arakunrin naa ti sa iyawo re ti n je Ziriya Nankwaga pelu ada.

Iroyin ni, wahala be sile ni ijeta, leyin ti Ziriya lọ lo ojo meta ni ile awon obi re ni Buyanga Sub County, ti ko jina si ile ti Ziriya ati oko re.

Ms Kamida Kagoya, omo odun aadorin, ti o je iya baba arakunrin naa ti o n ba oko ati iyawo naa gbe ni, nigba ti Ziriya pada si ile, oko re bere si ni fi esun kan pe o fe kuro ninu igbeyawo naa.

O ni awon mejeeji bere ariyanjiyan, oun si la won. Ms Kagoya ni ale ojo naa ti omo omo oun pada sile ni nnkan bi ago mejo ale, iyawo re ko kati si ilekun fun.

O ni bi oko se gbiyanju ati gba oju ferese wole niyen, o ni bi o se wole, o bere si ni lu iyawo re, o mu ada, o si fi sa iyawo re, o si fi sa omo won odun meji ti o wa nibe.

Olopaa adari agbegbe Bugweri lo fi idi isele naa mule, o ni o fi ge owo otun obinrin naa, bee si ni o sa omo naa ni itan.

O ni won ti n wa ibi ti arakunrin naa aa pamo si, pe enikeni ti o ba mo nnkankan nipa ibi ti arakunrin naa wa, ki o ma ko lati fi to awon leti.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…