Home Entertainment Kizz Daniel ti fi ẹ̀sùn kan Vanguard Newspaper.

Kizz Daniel ti fi ẹ̀sùn kan Vanguard Newspaper.

Gbajumo akorin omo Naijiria, Kizz Daniel ti lo ile ise ti won gbe orin re jade(Fly Boy Inc) lati fi esun kan Vanguard Newspaper , o n bere milionu lona ogorun naira lowo won nitori atejade ti o pe ni “atejade korira” ti won gbe jade nipa re.

Ni ose to koja, akorin na pe ile ise iweroyin naa nipa atejade ti won se pe, o fun won ni aye fun ifoworowanilenuwo nibi ti o ti n tako awon ti won n fi ehonu han si pasito COZA, Biodun Fatoyinbo, ti o wa ninu wahala esun ifipabalopo.

Orisirisi iroyin lo ni Kizz Daniel se iforowanilenwo nibi ti o ti pe awon ti n tako Fatoyinbo ni “alailopolo”.

Ninu leta ti awon lọya Kizz Daniel fi ranse si ile ise Vanguard, Kizz Daniel n beere fun ebe, o si ni ki won yo atejade naa kuro, ki won si ko akosile pe awon o ni te nkankan jade nipa re ayafi ti won ba koko beere nipa oro naa lowo oun, o si tun beere fun milionu lona ogorun naira fun atunse nnkan ti won ti baje nipa oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…