Home ÀKỌ̀TUN Àbájáde eré o̩ló̩s̩e̩ tuntun tí a pè ní “THE BARCHELOR” jáde lorí Startimes
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 12, 2019

Àbájáde eré o̩ló̩s̩e̩ tuntun tí a pè ní “THE BARCHELOR” jáde lorí Startimes

Àgbéjáde Eré Ọlọ́sẹ̀ tuntun tí a pè ní “THE BACHELOR” jáde lórí StarTimes

Níbi ọ́nà láti mú ìgbádùn rẹpẹtẹ fún àwọn olùwòran tó ń pọ́ síi lójojúmọ́, ilé-iṣẹ́ agbà ọ̀jẹ̀ Star Times ti ṣe àgbékalẹ̀ eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tuntun kan tí a ń pè ní ‘’ The Bachelor’’ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kejìlá, oṣù keje ọdún 2019 lórí ìkànnì ST Yoruba ìkànnì 412 àti 160 ní agogo mẹ́jọ alọ́ ní àkókò ilẹ̀ adúláwọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Aládarí Ètò StarTimes, Abọ́sẹ̀dé Adéwárá ṣe sọ, eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yí dálé ọ̀dọ́mọkùnrin olówó kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pada dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ìlú Amẹ́ríkà tó sì ní ìrètí láti bẹ̀rẹ̀ ìdílé pẹ̀lú ọmọbìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ sí láì mọ̀ pé ṣíṣe àṣeyọrí nínú ìgbéyàwó kọjá ẹwà, ọmọ tàbí bí ọkùnrín ṣe le ta tó lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin.

“Kò-ṣeé-má-wò ni eré ọlọsọ̀ọ̀sẹ̀ tuntun yìí nítorí pé ó ṣe àfihàn gbangba ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àrọ́wọ́tó o wa àti àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí tọmọdé-tàgbà le kọ́ níbẹ̀. Yó lárinrin púpọ̀, kìí sí ṣe èyí tí ẹ ọ wò lẹ́ẹ̀kan péré.

‘’StarTimes ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀-jigẹ̀ láàrin àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ nípa àwọn ètò tó múná dóko tí wọ́n ń ṣe, èyí yó sì tún mú òkìkí Star Times kàn sí i, tí yó wú àwọn olùwòran lórí, tí wọn kò sì ní gbàgbé ìrírí i wọn lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán.’’ Ó kádìí.

StarTimes

StarTimes ni adarí láàrin àwọn ogunlọ́gọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ amóhùn-máwòrán ní Áfríkà, tó ní àwọn tó ń pèsè fún ènìyàn bíi mílíọ́nù méjìlélógún, pẹ̀lú ìró-agbára tó la gbogbo Áfríkà já, àti ilé-iṣẹ́ igba tó ń ṣe agbátẹrù, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ilé ìrọ̀rùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún àwọn òǹtàjà ní orílẹ̀-èdè ọgbọ̀n. StarTimes ní onírúurú ètò, pẹ̀lú ìkànnì tó lé ní irinwó tó wà fún ìròyìn, eré, eré ìdárayá, fàájì, ètò-ọmọdé abbl. Àfojúsùn ilé-iṣẹ́ ni “Láti rí i pé ìdílé kọ̀ọ̀kan ní Áfríkà le jẹ àǹfàní, ní wò kí wọ́n sì le pín ìdùnnú tó wà nínú ẹwà Amóhùn-máwòrán ìgbàlódé”. StarTimes rí èyí ṣe nípasẹ̀ lílo àwọn ẹ̀rọ alátagbà tó bá ìgbà mu tó fi jẹ́ pé kò sí ìdádúró kankan fún àwọn olùwòran láti gbádùn àwọn ètò o wa. Ilé-iṣẹ́ ń pèsè ọ̀nà tó tayọ láti fún àwọn aládáni

àti àwọn míràn tí wọ́n ń lo wá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ni iàǹfààní láti jẹ́ pé iye ètò tí àwọn olùwòran bá fẹ́ ni wọn yó sanwó fún, àǹfàní láti wo ètò lórí ayé-lu-jára, ojúle-dé-ojúlé àti ọ̀nà láti sanwó tó rọrùn. Ní pàápàá jùlọ, ètò kọ̀mpútà tí a ń pè ní “StarTimes ON” jẹ́ ọ̀nà tó rọ́run fún àwọn ènìyàn láti wo ètò wa lórí ayé-lu-jára láì já owó wón ní ìjákújàá. Ẹ le mọ̀ síi nipa Star Times lórí startimestv.com

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …