Home iroyin NAFDAC ti ti àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n fi oògùn òkú toju ponmo.

NAFDAC ti ti àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n fi oògùn òkú toju ponmo.

National Agency for Food and Drug Administration and Control, NAFDAC, ti ti awon ile ise meta ti won ko ponmo wo ilu ti won wa ni Unity Avenue, Ijagemo; Sosanya Street ni Ijegun ati Adedayo Street ni WAZOBIA Bus Stop ni Abaranja, ti gbogbo wa labe Alimosho local government area ni ipinle Eko.

Won fi esun kan awon ile ise naape won lo oogun ti won fi n toju oku lati toju ponmo ti awon n je. Won gbe okan lara awon to ni awon ile ise naa, Isaac Nwaebo leyin ti o towo bo iwe ti NAFDAC le mo ile ise e. Igbakeji adari Intelligence Unit NAFDAC, Ogbeni Francis Ononiwu lo fi idi eri isele naa mule, o ni,

“Nigba ti a koko lo si ile ise Nwaebo ni ose to koja, awon ba pinmo repete nibe, a si ti ibe. Nigba ti a lo sibe ni ojo Tuesday, a o ri ponmo kankan nibe mo. O ni lati salaye bi awon ponmo ti o wa ninu ibi ti a ti se rin.”

“Opolopo ile ise to n ko wo ponmo wole lo wa ni Eko. Won si n fi oogun ti won n fi toju ponmo toju awon ponmo yii, ti ko si da fun ago ara awa eeyan. O ti n ba won ja tipe, a si ma ri gbogbo won ko.”

Iroyin ni awon ti n gbe ni Adedayo Ayodeji street ti n kero nipa okan lara awon ile ise naa. Punch royin pe, won ni oorun ti n jade lati inu ile ise naa o da rara.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…