Home ÀKỌ̀TUN Iró̩ ńlá ni, kò sí ìjàm̀bá iná gáàsì ní Ibafo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 18, 2019

Iró̩ ńlá ni, kò sí ìjàm̀bá iná gáàsì ní Ibafo

Iroyin eleje kan jade ni osan oni. Iroyin naa so wi pe ijamba ina gaasi sele ti o si di titi morose to lo lati Eko si Ibadan.
Awon oniro naa gbiyanju de bi wi pe won fi oruko oga awon eso oju ona FRSC si iroyin naa.
Won ni oun ni o so wi pe ki awon eniyan maa dari oko won gba ilu Sagamu tabi Abeokuta tabi Ikorodu tabi Sango nitori pe ko si ona lati koja.
Won ni ijamba naa buru de bi wi pe ko si aaye fun okada gan-an lati koja.
Nigba ti IROYIN OWURO de ibe lo rii daju pe iro nla ni. Awon osise Julius Berger ibe ni loooto ni irinse awon ko lu nnkankan ti ategun si fe jade. Won ni loju ese naa si ni awon ti da ategun naa duro.
Awon oniro yii ti gbee de bi wi pe awon eniyan ti bere si ni lo maa sare mu omo ni ile iwe. Won ti sare de odo awon oloja ni ilu Ibafo naa ki won tete maa palemo.
Ijoba ni lati ni agbara lori ero ayelujara ti a n lo yii ki iro maa baa gbajoba mo won lowo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…