Home iroyin Ọlọ́pàá gbé ọkùnrin ọmọ ọdún mọ́kànlélógójì fún ẹ̀sùn pé ó lú ìyàwó rẹ pa.
iroyin - orisiirisii - Orisirisi - June 12, 2019

Ọlọ́pàá gbé ọkùnrin ọmọ ọdún mọ́kànlélógójì fún ẹ̀sùn pé ó lú ìyàwó rẹ pa.

Awon olopaa ipinle Anambra ti gbe omo odun mokanlelogoji Sunday Ngwu, fun esun pe o lu iyawo re, Amara Ngwu, titi emi fi bo lara re ni ile won ni ikwo street ni agbegbe Idemili North local government.

Awon olopaa ni okunrin naa to wa lati Nkanu LGA ni ipinle Enugu, ni oro awo pelu iyawo re ti won bere si ni ja, o lu iyawo re gan, o si la irin nla kan mo lori.

Awon olopaa ti won wa ni Awada dividion gbo nipa isele yii nigba ti won gbe obinrin naa lo si ile iwosan ti awon dokita si ni o ti gbe emi mi pe ki won gbe oku re lo si mosuari fun ayewo.

Won si gbe oko re lesekese.

Komisona awon olopaa ni ipinle naa, CP Mustapha Dandaura, ti ni ki won gbe ejo naa lo si Criminal investigation department ti ipinle naa ni Awka, lati se ayewo to peye ki won to gbe okunrin naa lo si ile ejo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…