Home ÀRÒJINLẸ̀ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fún àwọn akọ̀wé láíláí(permanent secetary) mẹ́sàn-án ní ìwé gbéléẹ.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fún àwọn akọ̀wé láíláí(permanent secetary) mẹ́sàn-án ní ìwé gbéléẹ.

Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinle Ondo ti ni ki awon akowe lailai mesan-an ti ipinle lo feyinti ni dandan. A gbo pe lara won o ti pe ogota odun(60 years), to je iye odun ti won ma n feyinti,lara won naa o si ti lo to odun marunlelogbon(35years) ninu ise ijoba.

A gbo pe lara awon ti isele naa kan, ti gba leta ni ibeere ose, isele naa o ba lara won mu, won si ti ni awon ma gbe oro naa lo si ile-ejo.

Okan lara won so wi pe, o ni idi ti gomina fi se bee si awon, pe o yo awon kuro lati le fi aye sile fun eni ti o wun-un lati je olori ise (head of service), ogbeni Toyin Akinkuotu, ti won ni o ma feyinti ni osu kejo odun 2019.

Eni kan to je agba ninu ise ijoba ni idi ti gomina fi se bee ni pe,o fe fi eni to jerii se olori ise(head of service). O ni
“ nnkan to sele o ki n se tuntun ninu ise ijoba, nigba ti Mimiko wa nibe, omo Ondo lo fi se olori ise. Ti Akeredolu ba yan eni ti o wun-un fun olori ise, orun o ni ya bole, o ni agbara lati se e, o le yan enikeni ti o ba wun-un.

Nigba ti won bi komisona fun iroyin ati isalaye (commissioner for information and orientation), Yemi Olowokabi, o ni ijoba o ni ki awon eniyan yii gbele won, won ni ki won feyinti leyin ti won ti sise fun bi odun mejo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Arábìnrin ti da omi gbóná lu ọmọ.

Owo olopaati tearabinrin kan ti o da omi gbona lu oju ara omobinrin kekere kan ti n gbe ni…