Home ÀKỌ̀TUN Kò sáǹfààní fún e̩niké̩ni lati rúfin dàlú rú lásìkò mi – Seyi Makinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 30, 2019

Kò sáǹfààní fún e̩niké̩ni lati rúfin dàlú rú lásìkò mi – Seyi Makinde

Femi Akinsola

Yoruba ni o n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de, amọ ni ti gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde, oju lo fẹ mu to o, tori pe ikoko kan o ye ko foni lepo leemeji.
Idi ree to fi n lọgun tantan tan pe, ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero kankan abi ẹnikẹni to ba gbero lati fa wahala lẹsẹ lasiko ayẹyẹ ibura oun sipo gomina,nipinle oyo eyi ti yoo waye lọjọru, yoo jẹ iyan rẹ nisu.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Seyi Makinde, eyiun Ọmọọba Dọtun Oyelade fisita , lo sisọ loju eegun ọrọ naa.
Atẹjade naa tun n fi ewe ọmọ mọ igun ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW to ba gbero lati da omi alaafia ipinlẹ Ọyọ ru ki wọn to se ibura, lasiko ibura ati lẹyin rẹ, yoo ge ika abamọ jẹ.
Seyi Makinde ni oun ti n hu gbọ pe awọn eeyan kan ti n leri leka lati da rogbodiyan silẹ lọjọru Weside, to si n rọ awon igun ẹgbẹ NURTW to n se fanfa , lati ma je keefin ikunsinu won o ru tu u boode o, debi pe yoo fin araalu loju. O ni ofin o ni besubgba lati sise owo o re funrufe eni yoowu towo ba te.

Seyi Makinde wa fi ọwọ idaniloju sọya pe oun ko yan igun ẹgbẹ awakọero kankan nipọsin, nitori ko si ẹni to kọja ofin,pẹlu afikun pe oun ti kesi ileesẹ ọlọpaa lati fi imu ẹnikẹni to ba sokunfa rogbodiyan danrin.
Gomina naa wa n mu da awọn araalu loju, to fi mọ awọn iyalọja,babalaje atawon eeyan rere ipinle too lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ̀, ti ijọba oun si ti pinnu lati jẹ ki eto aabo fẹsẹ rinlẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…