Home ÀKỌ̀TUN AISHA BUHARI TÚN FA ÌBÍNÚ YỌ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 26, 2019

AISHA BUHARI TÚN FA ÌBÍNÚ YỌ

Lola Afolabi
Iyawo aare orile-ede wa, iya afin aisha buhari tun ti so oro gbigbona lori awon eto kan ti ijoba apapo se lori bi aye se le de awon ara ilu lorun.
Pelu ibinu ni aisha se so ni ojo satide pe awon eto naa ti ijoba na owo nla nla le lori ko so eso rere fun awon eniyan.
Lasiko ti o n ba awon obirin kan se apero pataki ni ijoba aso villa ni Abuja, o so pe eto amayederun ti won ko edeegberun billion naira le lori(500 billion naira), ko ni ipa kan kan ni opo awon ipinle.
O ni bi apeere ni ipinle oun Adamawa, opolopo awon obinrin ni ko ri kobo ni be.
Bakan naa, aisha ni ipinle kano, awon ijoba ipinle meji pere ni won je anfaani lara owo naa.
Ko tan sibe o, aisha tun so pe owo milionu dollar merindinlogun (16 million dollars) ti won ko lori aso idaabobo efon (mosquito net) oun ko mo bi won se se e.
Iyawo aare ni, ni t’oun o, oun ko ri apo efon Kankan.
O tun wa se ikilo pe owo bii igba bilionu ati aadota (250 billion naira) ti won tun sese ya soto lori ilera ko gbodo tun poora bi iso.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…