Home ÀKỌ̀TUN Neymar ti gbá bọ́ọ̀lù àádọ́ta wọlé fún PSG
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 5, 2019

Neymar ti gbá bọ́ọ̀lù àádọ́ta wọlé fún PSG

Leyin opolopo igbele latari ifarapa eleyii ti o se akoba lopolopo fun gbankogbi agbaboolu omo orileede Brazil n ni, Neymar, o kopa ninu ifigagbaga ti egbe agbaboolu re PSG ti koju egbe agbaboolu Nice ninu liigi akoko ti orileede France (Ligue 1) o si gba boolu eyokan eyi ti won fi ta omi ayo eleyo kookan (1-1) wo inu awon. Boolu ti Neymar gba wo inu awon yi ni o so apapo boolu ti o ti gba wo inu awon fun iko PSG di aadota (50goals) ninu ifigagbaga metadinlogota (57matches).
Ignatius Ganago ti o n gba boolu fun Nice ni o koko gba ami ayo kan wole PSG ni kope ti abala keji figagbaga naa bere ki Neymar to ri anfaani goli-womi-ngba-sio leyin ti Patrick Burner gbe Angel Di Maria subu, ti oun naa ko si fi jafara rara, o gba wole ni eye o so ka.
Se Yoruba ni o so wi pe ori ti yio gbeni ni n gbe alawo ire koni, sugbon sibe sibe, ti ori ba tun gbeni tan, ki Olorun je kiba ri enire ba da nnkan po ni! Ori gbe iko PSG ninu ifigagbaga naa nitori wipe o gbe adari ayo ti o mu goli-womi-ngba-sio ninu ifigagbaga kan soso sugbon won kori eni rere ba da nnkan po. O ku iseju die ki ifigagbaga naa pari ni adari ayo lo se abewo si ero amohunmaworan asofofo ninu ifigagbaga (VAR), abalo ababo, o mu goli-womi-n-gba-a-si o fun PSG eyi ti Edinson Cavani gba si owo asole fun iko Nice, Walter Benitez, ni oro ba di wo mi-n-wo-o ni ile awon PSG!
Lati igba die seyin ni nnkan o ti senu re fun iko PSG nitori wi pe ifigagbaga eyokan soso ni won bori ninu meje ti won ti gba seyin bayii, won ta omi meji, won padanu merin. Sugbon Saa, won ti gba ade idije liigi Akoko ti orileede France (Ligue 1) lati osu ti o koja nitori wi pe ami metadinlogun (17points) sangiliti ni won fi n siwaju egbe agbaboolu eyikeyi ninu liigi naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…