Home ÀKỌ̀TUN Boko Haram tún kó ènìyàn ní ilé-ìwé àwọn obìnrin ti Zamfara
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 2, 2019

Boko Haram tún kó ènìyàn ní ilé-ìwé àwọn obìnrin ti Zamfara

Yoruba bo, won ni “ti omo olowo ba saisan, won a ni ko roju jeun sugbon ti o ba je iwofa, won a ni o tun gbe ise re de”. Eyi lo sele ni ipinle Zanfara ni igba ti awon ajinigbe tun ya bu ile-iwe awon omobinrin nikan to wa ni ipinle naa. Won ko eniyan mefa. Awon mefeefa naa ni eni to n dana fun awon akekoo ni ibe to je okunrin ati obinrin pelu awon omo won ti apapo won si je mefa.
Bi isele yii se sele ni iroyin kan kaakiri gbogbo ilu ti awon obi si ya bo ile-iwe naa ni idaji oni nitori pe ale ana ni awon eniyan buruku naa ya bo ile-iwe naa. Awon eniyan naa ko tii beere fun nnkankan titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…