Home ÀKỌ̀TUN Ìdí tí mo fi run ìdílé ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi – Deji Adenuga
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 1, 2019

Ìdí tí mo fi run ìdílé ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi – Deji Adenuga

Lati bii ojo meta seyin bayii ni iroyin ogbenu Adedeji Williams Adenuga to dana sun ile obinrin afesona re, ti ina naa si run eniyan mejo ni Igbodigo ni ijoba ibile Okitipupa ni ipinle Ondo, ti gba igboro kan.
Ogbeni Adenuga koko fi papa bora,” se ibinu ko kuku mo pe olowo oun ko lese nile”. Ni ijeeta yii ni owo awon olopaa te ogbeni naa. O si bere si ni salaye “ohun to ri lobe to fi waro owo”.
Ogbeni naa ni igba ti ina ife awon si n jo, odo oun ni Titi Sanumi n gbe, o kan maa n lo si ile won ni ekookan ni. O ni oun si maa n toju re daadaa, o ni elegbe gbogbo ohun to ba beere ni oun maa n fun un. O ni ojo kan wa to gba egberun lona ogbon naira (N30,000), ojo kan naa wa ti oun ni ko ba oun ko egberun marundinlogbon (N25,000) miran lowo. O ni pelu gbogbo re naa, egbon iyawo oun to n je Jumoke maa n ko obinrin naa si oun ti o fi je wi pe gbogbo oun ti o n se lori obinrin naa ko wa joo loju mo. O ni bee si ni oun maa n nawo fun Jumoke naa.
Adenuga ni ju gbogbo re lo, obinrin yi loyin osu merin fun oun, oun ko si so pe agbara oun ko kaa. O ni sadede ni oun rii pe o ti ba oyun naa je ti o si ni oun ko se ti oun mo. O ni Jumoke tile ni ki oun lo mu egberun lona ogun naira wa ki iyawo le pada sodo oun. Oun si ni ki won fun oun ni asiko die ni won ba tun so oun di oniyeye. O ni oun ati Jumoke egbon re wa bere si ni fi oun se yeye. Won tile tun wa maa n dun ikoko moo oun pe awon maa pa oun. O ni eyi mu ki oun lo fi ejo won sun ni ago olopaa sugbon awon olopaa ko ri nnkan gidi se si oro naa. O ni eyi bi oun ninu, o si mu ki oun sinu bi si idile naa.
Igba ti isele yii sele ni awon olopaa to wa rii pe odaran paraku ni okunrin naa. Won tu iwe kan oruko re pe oun lo pa iyawo akoko re ni odun 2000 ti o si fi di ero ewon ni odun naa. Won ni odun 2003 ni wahala kan sele ti awon elewon wo iganna ogba ewon ti awon kan si sa jade ti o tumo si wi pe o wa ninu won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…