Home ÀKỌ̀TUN APC àti PDP tún gbéná wojú ara wọn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 26, 2019

APC àti PDP tún gbéná wojú ara wọn

Ikolura-eni nipa oro koba ikun gbe lati bii odun merin seyin bayii laarin egbe oselu meji to moke ju, egbe APC ati PDP. Ojumo kan ede aiyede kan ni. Owuro oni ni alaga egbe oselu PDP, Alagba Uche Secondus ba oniroyin soro ti si n salaye pe gbogbo nnkan ti daru mo egbe oselu APC loju. O ni ko dara rara bi Aare Muhammadu Buhari se lo si idale ni asiko ti ilu re n gbona janjan.
Secondus ni ilu ko tii baje to bayii ri lati igba ti oun ti daye. O ni bi o tile je pe “eru naa ni egbe APC fi n gba ibukun”.
Ogbeni Lanre Issa-Onilu to je alaga agba fun egbe oselu APC da Alagba Secondus lohun kiakia. O ni ko si oro ninu ohun ti alaga naa so, o ni gbogbo omo Naijiria lo ti mo won pe, won kan maa n wa iwara kiri ni, won si maa n fe je ki araye mo pe egbe naa ko tii ku patapata ati pe ki won le han ninu awon iwe iroyin wa gbogbo.
O ni ko si oro Kankan ninu ohun to so nitori pe omo Naijiria gan-an mo bi ilu se baje to ki egbe oselu awon to gbaa. O ni ko si eni to towo bo won lenu ti won fi bebe pe ki omo Naijira o fori ji awon, nigba ti awon naa mo ose buruku ti won ti fi emi omo Naijiria gun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…