Home ÀKỌ̀TUN Ọmọ Yinka Quadri lu Sunny Ade ní jìbìtì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 21, 2019

Ọmọ Yinka Quadri lu Sunny Ade ní jìbìtì

Alabasise po gbajumo osere ti gbogbo aye mo si Yinka Quadri ni “omo ose tii ko kunmo ba iya re” ti fi erofo yi ni aso. Arakunrin Femi Oyedokun ni o je P . A gbajumo osere naa lati odun to ti pe.
Arakunrin yii wa bere si ni lo ero ayelujara fi gbowo lowo awon ara ilu kiri. O ni Sunny Ade ni ode kan ni oke okun, o si nilo iranlowo awon ololufe re, eyi ni awon oloolufe ri ka ti won fi bere si ni “lari mọ ọ”.
Femi oyedokun ti gba owo milionu naira to loruko ki “oka to fo”. Awon to sun mo King Sunny ade daadaa ni won gbaa laago pe igba wo lo bere ohun ti o lu igboro kan yii. Won ba ni ki o wo ikanni naa, ni oun naa ba rii pe won ti fi oruko oun lu jibiti repete. Kia ni o be awon olopaa lowe ki won ba oun sọdẹ awon eniyan naa.
Ko pe pupo ti owo awon agbofinro fi te Ọgbẹni Femi Oyedokun, Arabinrin Rebecca to je ololufe Femi pelu ore re kan ti oruko re n je Oyewumi. Awon meji to ku tile ṣẹ pe awon ko mọ pe jibiti ni o n lu, won ni awon ro pe o n sise fun Oba orin ni. Nigba ti Femi de ago olopaa, o ni oga oun Yinka Quadri ko tilẹ mọ nipa iṣẹ buruku ti o n se naa. Eyi ni o yọ okun lọrun ọ̀gá rẹ̀ sugbọn ko si bi won se fe daruko Aja ti won ko ni daruko ikoko ti wọn fi sèé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…