Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ tẹ oníjìbìtì tó gbé ilé kan fún ènìyàn 125
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 15, 2019

Ọwọ́ tẹ oníjìbìtì tó gbé ilé kan fún ènìyàn 125

Ilu Agege ni ipinle Eko ni owo ti te Ibrahim Hamidi Ayinde to n sise abaniwale. O gbe fulaati oniyara meta kan fun eniyan marunlelogofa. Oka fo ni ojo kan ti okan ninu awon to ba wale ko eru lo si fulaati naa. Igba ti eni naa de ibe ni o tun ba elomiran to n gbe ile naa.
Eyi mu ki o pariwo sita. Ko pe pupo ni awon miran naa tun ko ija de pe awon ti pari owo ile awon sugbon awon ko tii ri kokoro ile gba. Awon tile ni gbogbo kokoro lowo ti won ko ri ile wo. Eyi mu ki ikede jade lori ile naa pe gbogbo eni to ba san owo fun arakunrin Hamidi yoju. Ko pe osu kan ti eniyan marunlelogofa fi yoju lori ile kan naa.
Ibrahim Hamidi je omo odun mokandinlogoji, o ni ki adajo se oun jeje, o ni ko si iro ninu oro awon eniyan naa sugbon oun ti bere si ni da owo won pada diedie.
Onidajo ojo naa, Arabinrin O.A Olagbende ni ki arakunrin naa wa ni galo awon olopaa to wa ni ilu Ikoyi fun ose kan ki igbejo to te siwaju ni ojo kokanla, osu kerin, odun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…