Home ÀKỌ̀TUN Buhari bá ìpínlẹ̀ Èkó kẹ́dùn iléèwé tó dàwó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 13, 2019

Buhari bá ìpínlẹ̀ Èkó kẹ́dùn iléèwé tó dàwó

Osan oni ni iroyin buruku naa gori afefe nipa ile alaja meta kan to dawo ni adugbo Ita-faji ni ipinle Eko. Ile naa ni won ni awon ileese kan wa ni isake re patata, awon miran wa ni aja akoko nigba ti ileewe wa ni aja to gbeyin.
Ibanuje nla ni eleyii je, gbogbo eleran ara to gbo, koda gomina ipinle Eko , Akinwunmi Ambode ti sare de ibe. O si parowa fun awon ero to wa nibe ki won jowo je ki awon osise to n yo awon omo naa raaye sise.
Kia ni Aare Buhari naa ti gbe onise dide lati ba ipinle Eko kedun awon emi aise to wa ninu ijamba naa.
Bi gomina ti wa ni ibi ti ile ti dawo ni igbakeji re naa ti gba ile iwosan ti won ko awon ti won yo ninu ijamba naa. Pelu ibi ti won ba igbiyanju didoola emi de nibe, eniyan mejo lo ti ba isele naa lo. Gbogbo abiyamo lo kawo lere nibi isele buruku yii, awon to lomo nibe ni ki a so ni abi awon ti itara omo ko je ki won gbadun. Ki Eledua ba wa dawo aburu duro.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara Orẹ Òtítọ́jù Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pà…