Ibo Adelabu ati Seyin Makinde n da robirobi sile ni Ipinle Oyo
O soro fun enikeni lati so pato bi nnkan yoo se ri ni Ipinle Oyo lasiko ibo gomina to n bo.
Idi ni pe awon oludije mejeeji to wa niwaju, iyen Adebayo Adegoke ti APC ati Seyi Makinde ti PDP, jo lero leyin ni.
Teletele, opo eniyan gba pe ko nii soro fun APC lati gbegba oroke, sugbon ohun to sele lasiko ibo Aare ati asofin agba to lo ti mu ki won maa tero pa.
Leyin pe Atiku Abubakar ni ibo ju Aare Muhammadu Buhari lo, Gomina Abiola Ajimobi kuna lati wole ninu ibo Seneeti.
Pelu eyi, APC naa wa ri i pe ise po funwon lati se.
Igbese kan pato ti yoo ran won lowo ni ti Gomina tele, Alao Akala, to pada si APC. Pelu eyi, o jo pe won yoo ribo daadaa ni Ogbomoso.
Sugbon sa o, PDP naa ko kawo gbera. Awon naa si ti ri ibukun lati odo awon agbarijo egbe oselu to ku, ti won ni ti Makinde lawon yoo se.
Ohun ti a tun wa n ri ni pe die lara awon omo egbe miran naa tun ti n se atileyin fun Adelabu.
Lara won ni awon to dije fun ile igbimo asofin ni Zenith Labour Party, to fi mo Semih Alao.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…