Home ÀKỌ̀TUN Àjọ EFCC dáwọ́ ìwádìí lórí bàlúù tó gbówó dúró
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 2, 2019

Àjọ EFCC dáwọ́ ìwádìí lórí bàlúù tó gbówó dúró

Ajo EFCC to n fowo sinkun ofun mu awon to ba se owo ilu maku-maku ni agbara kan lati oke ti da lowo duro lori baluu kan ti owo akoju ko je ki o le fo mo ni papako ofurufu Muritaka Mohammed to wa ni ilu Ikeja.
Iroyin gbee pe owo naa pọ de bii wi pe ko si bi baluu naa se le ko owo naa ki ijamba ma se sele lona. Won ni ilu Ilorin ni awon alagbara n ko owo naa lo ni ojo keedogun osu keji odun ti a wa yii. Ojo naa ni ojo idibo Aare ku ola ki won to sun ojo idibo siwaju ni oru ojo naa.
Gbogbo igbiyanju lati mo eni to lowo ati ọdọ eni towo n lo ni ilu Ilorin ati eni to ni ki ajo EFCC dawo iwadii duro lo ja si pabo. Alukoro ajo naa, Ogbeni Toni Oriade ni oro owo naa ko ye oun rara, nitori pe ori ero ayelujara ni oun ti n gbo gbogbo oro owo naa. O ni ko tii si faili esun owo naa ni ajo awon.
Nigba ti aroye awon eso papako ofurufu naa po ni awon Soja gba ijoba papako naa ni ojo naa, nigba ti o fi maa di aago mewaa ale, won ti wa baluu miran to lagbara , o si gbe owo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…