Entertainment - Orisirisi - February 23, 2019

Baba Suwe pariwo sita: E gba mi, e ma je ki n ku bayii

Asiko niyi ki awon ti won ba nifee gbajugbaja apanilerin-in, Babatunde Omidina, eni ti a mo si Baba Suwe, ni lati dide iranwo si i.

Idi ni pe ailera nla kan ti da a gunle, to si je pe o ti gba gbogbo owo to wa lowo re.

Wahala naa bere nigba to lo si orile-ede Amerika nibi to ti dede subu lule.

Gbogbo ipa ti awon eniyan sa nibe pe ki ara re fi ya lo ja si pabo.

Nigba to n se alaye wahala to ba a fun agba oniroyin kan, Kola Olotu, o ni latigba ti oun ti oun ti pada wa si Naijiria ni won ti n taari oun lati osibitu kan si ekeji.

O ni bee, igbadun ko pada si ara oun. Nnkan buru fun Baba Suwe bayii debi pe o ti fee dara nu, eni to sigbonle daadaa tele.

Koda, ko le da rin mo, opa lo n lo bi arugbo.

O ni ara ohun to se akoba fun oun ni iya ti ajo to n gbogun ti oogun oloro – NDLEA – fi je oun ni nnkan bii odun mefa seyin, nigba ti woun gbe oun ju si atimole, ti won da wiriwiri boo un tori won ro pe oun gbe oogun oloro sikun.

Ohun to wa se koko julo nip e Baba Suwe nilo iranlowo omo Naijira. O n fe iranwo owo to le fi se itoju ara re ni osibitu.

Nipa bee, gbogbo oun ti e ba ni, e ba a fi si a-ka-n-ti yii, ni First Bank:

FIRST BANK

Name: BABS OMIDINA COMEDY

NO: 2003537811

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…