Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ ọmọ Yahoo mẹ́fà pẹ̀lúu pátá Igba
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 21, 2019

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ ọmọ Yahoo mẹ́fà pẹ̀lúu pátá Igba

Kaka ki ewe agbon de, lile koko lo tun n le koko sii. Pelu gbogbo epe ati ikilo awon olopaa ati awon oba alaye kan nipa awon omo onijibiti ti won n lo pata awon obinrin fun aajo owo.
Aipe yii ni owo awon olopaa ipinle Delta tun te awon odokunrin mefa peluu pata obinrin igba (200). Awon oogun orisiirisii ati ibon ilewo wa lowo awon odokunrin yii.
Nigba ti owo te won ni won bere si ni ka boro-boro, won ni babalawo kan ni Ijebu-ode, ipinle Ogun ni awon n sise fun. O si ni iye ti pata kan je ti awon ba ti koo de ibe. Awon onijibiti naa ni – Chuks Okolie,Francis Ogbereh, Collins Ederah, Felix Nnamdi, Goodluck John ati Steve Akpokona.
ASP Chuks Orisewezie si jeri sii, o ni awon afunrasi naa ti wa ni kolo awon olopaa ni Okpanam, ipinle Delta.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari

Nàìjíríà sì nílò Ọbásanjọ́ fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari Fẹ́…