Home ÀKỌ̀TUN Ominú ń kọ ọmọ Nàíjíríà lórí ìbò tí INEC sún síwájú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 17, 2019

Ominú ń kọ ọmọ Nàíjíríà lórí ìbò tí INEC sún síwájú

Gbogbo ara ile ati ara oko lo ti gbaradi fun eto idibo to ye ko waye ni oni ojo kerindinlogun, osu keji odun 2019. Oro eto ibo yii n fun awon oniroyin lara ni nnkan bi ose meji seyin, won bi Olori eto idibo naa, Ojogbon Mahmood Yakubu, o ni ko si ohun ti o joo sisun-si-iwaju nitori pe awon tete bere.
Gbogbo awon omo agunbaniro ni o ti gba bi ti onikaluku ye ko duro si lati se iranlowo fun awon ajo INEC lo. Ibi ti won pin onikaluku si ni opo sun moju.
Ijoba ipinle lorisiirisii ati ti ijoba apapo ni abala eto eko ni won ti kede isinmi lorisiirisii. Opo ileewe ni won ti yi isinmi aarin saa won si asiko yii. Awon omo ileewe ti wa ni ile lati ojo Ojo’ru tii se Weside pelu ireti ati wole pada ni ojo Isegun tii se Tuside.
Awon kan tile ti pada si ilu won nitori ifunra won si awon agbegbe kan ti eto ibo le ma te won lorun. Awon kan pada si ilu won nitori iriri ati iroyin ohun to sele ni odun 2015.
Iyalenu nla lo je ni idaji oni ojo ti gbogbo aye n reti lati dibo pe ajo INEC ti so ojo idibo Aare ati ti ile igbimo asofin agba di ojo ketalelogun, osu yii, ni eyi tii se ojo Abameta to n bo. Nigba ti won sun ti awon gomina si ojo kesan-an osu keta odun yii.
Idi ti won fi se bee ko te opo omo Naijiria lorun. Won ni ko dabi awon ti won ti n sun siwaju pelu idi pataki.
Aare Buhari tii se oludije du ipo Aare labe egbe oselu APC ni inu awon ko dun si sisun-si-iwaju naa. Alhaji Atiku Abubakar tii se oludije du ipo Aare labe egbe oselu PDP naa fa ojuro si isele naa, koda olori egbe oselu naa tile fi ibinu so pe ki Ojogbon Mahmood Yakubu kowe fi ise naa sile.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…