Home orisiirisii Ìjọba àpapọ̀ kéde pé àrùn ibà lassa ti gbòde
orisiirisii - Orisirisi - January 23, 2019

Ìjọba àpapọ̀ kéde pé àrùn ibà lassa ti gbòde

Oni ojo ojo’ru, ojo ketalelogun osu kinni yii ni awon eleto ilera ijoba apapo kede pe ki gbogbo ara ilu so ara won ki won si kun fun imototo to peye.
Awon eleto ilera ni asiko eerun ni arun naa maa n gbile, ti o tumo si pe ki gbogbo ara ilu mo ipile ohun ti won maa je ati ohun ti won maa mu. Ki ara ilu si je ki ijoba apapo tabi awon eleto ilera tete mo ti won ba kefin arun to jo arun iba buruku naa.
Ijoba ni ki a sora paapaa laarin asiko yii si inu osu kerin ki o to di wi pe ojo gbile daadaa ti o si maa le arun naa wole patapata.
Won si se iranti arun naa pe ki a sora fun eku tabi ekute ninu ile nitori pe iwadii fihan awon eleto ilera pe eku lo n gbe arun naa si ara eniyan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun Ọrẹ Òtítọ́jù Minisita ọrọ abẹle…