Home Orisirisi Atiku ni ejo jibiti ti yoo je to ba ti Amerika de – Lai Mohammed
Orisirisi - Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - January 19, 2019

Atiku ni ejo jibiti ti yoo je to ba ti Amerika de – Lai Mohammed

Minisita fun Oro Oroyin at Asa, Alhaji Lai Mohammed, ti so pe Alhaji Abubakar ni ejo jibiti ti yoo je ni kete to ba ti orile-ede Amerika de.
Lati ijeta ni Atiku, eni to je oludije ibo aare fun egbe PDP, ti yo gule ni Amerika, eyi to ti fa opo awuyewuye.
Ohun ti a gbo tele ni pe o ni ejo lati je to ba wo orile-ede naa, ati pe bi eni gbe eja ni won yoo se gbe e latari esun riba kan.
Sugbon nnkan yi biri nigba ti Atiku te baalu leti lo si Amerika, pelu awon omo egbe PDP bii Dokita Bukola Saraki ati Senito Ben Bruce.
Nigba to n soro lori isele naa, Mohammed ni ibi to ba wu Atiku ko lo, ojo to ba si wu u ko lo ni Amerika.
O ni ohun ti oun mo ni pe ijoba apapo ti ri eri to daju pe Atiku gba owo to to N156m lona aito lati owo Habib Bank to di Keystone Bank bayii.
Sugbon sa o, Atiku naa ti so pe Ijoba Apapo ati egbe won APC kan n pala enu ni o, ati pe oun ko je banki naa lowo kankan

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…