Atiku wọ̀lú Amerika lẹ́yìn ọdún kejìlá
Igbakeji Aare tele ri ni orileede yii, Alhaji Atiku Abubakar ni orisiirisii awuyewuye ti kaakiri nipa re. Won ni ko to eru ti n wo ilu Amerika mo, won ni lojo to ba dan an wo, won maa fi owo sinkun ofin mu u ni.
Atiku Abubakar si n dije du ipo Aare labe egbe oselu PDP, awon eniyan ni to ba da ara re loju ki o gba orileede Amerika lo leyin odun kejila to ti lo gbeyin. Eyi ni o faa ti Atiku Abubakar fi te oko leti lo si ilu naa. Atiku fi ofo Yoruba senu, o ni “ ibi ti a ba ni ki gbegbe ma gbe lo n gbe, ibi ti a ba ni ki tete ma te lo n te …”.
Oludije du ipo Aare naa ko da lo, o lo pelu awon oloselu nla-nla bii olori ile igbimo asofin agba, Alhaji Bukola Saraki ati awon oloselu jankan-jankan miran.
Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò
Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…