Home orisiirisii Ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun sèlérí láti ṣẹ́gun ọ̀tá fún Nàìjíríà
orisiirisii - Orisirisi - January 15, 2019

Ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun sèlérí láti ṣẹ́gun ọ̀tá fún Nàìjíríà

Oba mewaa, igba mewaa ni oro ile aye yii. Eyi lo difa fun Ibrahim Idris to je oga olopaa patapata tele ni ilu yii. Oun ni o ti wa pe ogota odun ti eto ofin la kale pe eniyan ko gbodo lo ju bee lo lenu ise ijoba.
Ofin naa so pe ti eniyan ba lo odun marundinlogoji lenu ise ijoba tabi ki o pe ogota odun loke eepe, o ni lati feyinti ki o si gba awon owo ifeyinti ati awon eto miran lowo ijoba.
Mohammed Adamu ni ijoba Aare Mohaammadu Buhari fi ropo Ibrahim Idris gege bi adele oga olopaa patapata.
Oga olopaa tuntun yii ni oun mo ibi ti bata ti n ta Naijiria lese, oun si maa segun awon olote naa.Oni ni Aare Mohammadu Buhari kede re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…