Home iroyin O ma se o! Legacy, oga awon NRTW, ku iku gbigbona
iroyin - Orisirisi - January 9, 2019

O ma se o! Legacy, oga awon NRTW, ku iku gbigbona

Nigba ti Ogbeni Imail Afeez n lo si ibi ipolongo ibo awon APC ni ana Ojo Isegun, ko mo pe ijade ikeyin ni oun n ja.
Ko mop e ipolongo ibo ikeyin ni oun fe lo dara po mo.
O da gbere fun iyawo ati omo pe o dabo, sugbon eni Kankan won ko mop e ‘O digba, o di gbere’ ni awon jo wi fun ara awon.
Idi nip e okunrin naa ti di oloogbe bayii.
Iku moto ko lo pa a, bee kii se eje ruru.
Kii sii se pe awon kan ni won pe e ni apepa.
Dipo bee, o won yin in nibon ni.
Oun ni eni ti o ku iku ojiji latari rogbodiyan to be sile nibi ipolongo ibo naa, eyi to waye nikeja.
A gbo pe agbari ni won ti gbebon fun un, to si je pe osibitu ijoba LASUTH to wa ni Ikeja lo ku si.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun Ọrẹ Òtítọ́jù Minisita ọrọ abẹle…