Home orisiirisii Hijab dájà sílẹ̀ láarin agbẹjọ́rò nílé ẹjọ́
orisiirisii - Orisirisi - January 9, 2019

Hijab dájà sílẹ̀ láarin agbẹjọ́rò nílé ẹjọ́

Yoruba bo won ni ‘ibere ija laa mo, a kii mo ipari re”, won tun ni “oro kanle kan Baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi”. Eyi lo sele ni ile ejo giga to wa ni Isabo, Abeokuta.
Omodebirin kan ti oruko re n je Aisha AbdulAleem ni o pe ijoba ipinle Ogun lejo pe won ta ko eto omoniyan oun nipa siso pe ki oun ma se lo Hijab ti o n fi n bo eledaa oun gege bi o se wa ninu esin oun. Aisha je omo ile-iwe Gateway Junior Secondary ni Abeokuta.
Omo yii gbe ijoba apapo lo si ile ejo, o si ni ijoba gbodo san milionu kan naira owo itanran. Ejo yii mu ki opo elesin musulumi ati awon elesin kirisiteeni po ninu ile ejo naa.
Nigba ti awon agbejoro mejeeji bere, Israel Awofeso ni agbejoro ijoba nigba ti Sulaiman Akinbami je agbejoro Aisha. Agbejoro ijoba ni ki adajo je ki awon sun ejo si ojo miran nitori pe imura oun ko tii to, eyi mu ki agbejoro Aisha soro si ekeji re pe ko kun oju osuwon to lo je ki o fe sun ejo naa siwaju. Eyi lo mu ki inu bi agbejoro ijoba pe abuku nla ni ekeji oun fi kan oun, opelope adajo to ko si won laarin ni ko je ki ejo naa ju bee lo.
Adajo Bamgbose Alabi ni ejo yii ko ni pe pari. O si sun ejo naa si ojo kerindinlogun, osu kinni odun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…