Home orisiirisii Buhari kọ́ ló niwá – Keystone Bank
orisiirisii - Orisirisi - January 9, 2019

Buhari kọ́ ló niwá – Keystone Bank

Lati igba ti ipolongo ibo ti bere paapaa julo, ibo Aare ni orisiirisii ikoluni, idunkooko mo, iwe eninni ati onirunru esun ti n lo nigboro. Gbogbo eleyii n waye lati din ero ku leyin alatako.
Ara awon esun ti igbakeji Aare tele ri ni orileede yii, Alhaji Atiku Abubakar fi kan Aare Buhari ni pe owo re ko mo to bi o se n pariwo igbogun ti iwa ibaje lawujo. O ni ki awon omo Naijiria loo se iwadii to gbopan lori ile-ifowo-pamo si Keystone ati elero-ibani-soro Etisalat to di 9mobile bayii.
Eyi lo mu ki awon alakoso banki naa ke gbajare saraye pe Buhari tabi molebi re kankan ko ni ipin ninu ile-ise ifowo-pamo si naa. Won ni – “Sigma Golf Nigeria Limited ati Riverbank Investment Resources Limited” lo ni Keystone Bank.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun Ọrẹ Òtítọ́jù Minisita ọrọ abẹle…