Home orisiirisii Gómìnà b’ọkùnrin jẹ́ lójú Buhari
orisiirisii - Orisirisi - January 7, 2019

Gómìnà b’ọkùnrin jẹ́ lójú Buhari

Wahala Boko Haram ojooojumo ti mu ki asilewo ba gomina ipinle Bornu, Kashim Shettima. Eyi lo mu ki o ko awon eniyan sodi lati lo salaye ara re fun ijoba apapo.
Alagba Shettima ni awon eda bururku to n je Boko Haram ti doju so ipinle oun ju. O ni “akuku joye kuku san ju enu mi ko ka ilu lo”.
O ni gbogbo iranlowo ti ijoba apapo ba mo ni ki o se fun ipinke naa. O ni nnkan buruku ni ki oun maa gbo pe won pa awon eniyan ti o n se ijoba le lori ni gbogbo igba.
Shettima ni ki oun ma paro ki oun si ma jale, ipinle Bornu gbe osuba rabade fun ijoba Buhari nitori pe ki Buhari to de, awon Boko Haram ti gba ijoba ipinle naa tan. O ni opeleope Aare Buhari ni awon se n ri orun sun bayii. O ni bawo lo se tun wa je ti awon eniyan buruku naa tun bere si han awon ni eemo. Ibi ti gomina soro de niyi ti omi fi n jade ni oju re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…