Home iroyin Isẹ́ Buhari ni wọ́n fi máa dìbò fún un, kìí ṣe ọ̀rọ̀ tútù – Atiku
iroyin - January 2, 2019

Isẹ́ Buhari ni wọ́n fi máa dìbò fún un, kìí ṣe ọ̀rọ̀ tútù – Atiku

Eto idibo bii osu meji si asiko yii ti n fa ita-ohun-si ara eni laarin egbe oselu meji to n leke lowo-lowo, awon egbe naa ni egbe oselu APC ati PDP.
Ti Aare Buhari ba wuko, Atiku Abubakar maa ni bi olori se n wuko ko niyen. Bi Atiku naa bo so pere, Aare Buhari naa le ni iso naa ti run ju.
Eyi ti wa gbode kan, bi Aare Buhari ko dahun, awon olutele re maa da Atiku tabi awon olutele Aiku lohun.
Koda opo ile ijosin ni won ko ni iwaasu miran bi ko se oro nipa ibo Aare to n bo lona.
Bayii, Atiku Abubakar ni ki Aare Buhari ye polongo igbe aye alaafia ati ileri ibo ti ko ni si eru tabi konu-n-koho. O ni ki Aare Buhari lo kilo fun awon eso orileede yii ki won ye se ojoro. Ki won ye fi igba kan bo okan ninu paapaa julo Ibrahim Idris to je oga olopaa pata-pata.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…