Home iroyin 2018, odun ti Baba Sala, Sophie Oluwole, Ras Kimono rorun aremobo
iroyin - January 1, 2019

2018, odun ti Baba Sala, Sophie Oluwole, Ras Kimono rorun aremobo

Odun 2018 je eyi to mu awon eniyan nla kan lo.
Lara won ni baba agba ninu awon alawada, Alagba Moses adejumo, ti opo eniyan mo si Baba Sala.
Baba naa lo da erin pa eeke opo eniyan fun opolopo odun, pelu ere ori itage, ere ori telifisan ati fidio to se.
Bi o tile je pe ko se fiimu mo nigba to ya, to si dagba ki olojo to de, iku re ko sai dun opo eniyan.
Bakan naa, omowe Pataki kan, Ojogbon Sophie Oluwole, di ara ile nigba to ku die ki 2018 pari.
Ile re ni Ibafo ni opin de si fun obinrin iya to maa n ko gbogbo eniyan nipa asa ati ise Yoruba.
O di oloogbe leyin aisan ranpe.
Ti bi a ti n soro yii, won ko tii sin iya naa.
Ninu odun to lo naa ni akorin rege kan, Ras Kimono, je Olorun nipe. Iku re dun opo eniyan tori ko darugbo, eni ogota odun ni.
O tun wa dunni jojo pe kop e to s ku naa ni iyawo re se alsisi.
Iku kan to tun m ilu titi ni ti arabinrin Tosyn Bucknor.
Sorosoro lori redio ni, to sit un maa n se awon ise alariya miiran.
Arun aromoleegun lo se e, ti iku re si ka opo awon akegbe re lara.
Odun tuntun ti a wa mu yii, ki Olorun o ba wa da iku aitojo duro.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…