Home LÁGBO ÀRÍYÁ Salawa ranti orin to ko nigba ti ija be sile laarin oun ati Kollington Ayinla
LÁGBO ÀRÍYÁ - Orisirisi - December 31, 2018

Salawa ranti orin to ko nigba ti ija be sile laarin oun ati Kollington Ayinla

Akorin waka, Salawa Abeni, n gbona janjan lowo yi ni o. O se kisa ni ilu Eko lenu ojo meta yii, nigba to korin ninu eto nla kan ti won pe ni One Lagos Fiesta.
Ijoba Eko lo gbe eto naa kale ki awon eniyan le jegbadun odun Keresi ati Odun Tuntun.
Salawa korin ni Agege, o korin ni Ikorodu, bee lale Monday, o dabira ni Epe Onikurani, ilu ti won bi i si.
Gbogbo awon orin aladun re lo ko, sugbon okan wa to mu ki awon ololufe re to wa nibe o ranti awon ogun to ti la koja.
Eyi ni orin to ko ninu awon ‘Experience’, eyi to se nigba ti ija be sile laarin oun ati Alhaji Kollington Ayinla, leyin ti won ti fe ara won, ti won si bimo fun ara won.
Nigba ti ina jo ile Kollington, okan lara awon iyawo re kekere, Iyabo, ku lojiji. Won wa so pe Salawa lo ni ko se oyun to ni nitori ajalu naa.

Eyi fa ki inu Salawa baje, to si wa ko o lorin pe bawo ni orogun se fe so fun orogun pe ko lo se oyun.
Lai foro gun, oro naa lo fa bi o se fi ile Kollington sile.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…