Home ÀKỌ̀TUN Bàbá mi ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Buhari kó tó kú – Bala Shagari

Bàbá mi ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Buhari kó tó kú – Bala Shagari

Daodu oloogbe Shehu Shagari, Alhaji Bala Shagari lo n ba ajo
oniroyin “News agency of Nigeria” soro laipe yii. O ni tipe-tipe
ki baba oun to ku ni o ti dari ji Aare Muhammadu Buhari ati
awon miran ti won sẹẹ ni ọna kan tabi omiran.
O ni isejoba Buhari ni o fipa gbajoba lọwọ baba oun ni odun
1983 pelu aso ologun.
Ana ojo Aiku, ogbon ojo ninu osu kejila yii ni Buhari ko awon
eniyan sodi lo si ile Shagari lati lo ba ebi naa kedun Aare ana to
je Ọlọrun nipe.
Alhaji Shehu Shagari ni Aare alagbada akoko labe egbe oselu
NPN, o si jawe olubori ni odun 1979 titi di odun 1983 ti o tun
wole ibo eleekeji ki ijoba ologun to gba ijoba.
Shehu Shagari daye ni ojo keedogbon, osu keji odun 1925 ki
olojo to de ni ojo kejidinlogbon, osu kejila, odun yii. Aare
Shagari lo odun metalelaadorun (93 years) loke eepe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…