Home LÁGBO ÀRÍYÁ Bois Olorun ti Ibadan wa dabira l’Ekoo
LÁGBO ÀRÍYÁ - December 30, 2018

Bois Olorun ti Ibadan wa dabira l’Ekoo

Ni igba kan, akorin kan wa ni igberiko Ibadan. Oruko re ni Ayanyemi Ayinla, Atokowagbowonle.
O maa n fi ilu pa owe, ti awon elegbe re yoo si maa forin tumo re.
O pe ara re ni atokowagbowo-nile nitori o maa n lo sere ni ilu Ibadan, ti yoo si ma pa owo gidi gan-an.
Ni ti awon okunrin akorin meta kan ti won pe ara won ni Boisi Olorun, lowolowo yii, won n ti Ibadan gbowo ni Eko ni.
Awon Boisi Olorun yii ni won n fi apala ko orin emi, ti orin won si maa n dun morain-moroinin.
Won n kopa ninu ere asekagba odun ti won n pe ni One Lagos Fiesta, eyi ti ijoba Ipinle Eko gbe kale.
Awon Bois Olorun ti sere ni Epe ati Badagry, ti opo eniyan si dunnu si bi won se fi orin emi, apala ati awada se kisa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…