Home Orisirisi Ewo ni Buhari fe se ninu ti Amosun ati Oshiomhole?
Orisirisi - Ọ̀RỌ̀-ÒSÈLÚ - December 25, 2018

Ewo ni Buhari fe se ninu ti Amosun ati Oshiomhole?

O ti daju bayii pe Gomina Ibikunle Amosun ati Alagba Adams Oshiomhole ti da iyemeji si okan Aare Muhammadu Buhari.
Ija ajadiju ti Amosun ati awon alase egbe naa n ja ni Ipinle Ogun lo fa eyi.
Laarin Alaga egbe naa, Adams Oshiomhole, iyen Oshiomhole, ati Amosun, ofon-on ti to si gbegiri, onikaluku ti ko eko re lowo.
Oshiomhole ni Dapo Abiodun ni Ifa ibo gomina abele mu. Amosun taku jale, o ni Akinlade ni, eyi to fa ti won fi lo si egbe APM.
Amosun ti so pelu idaniloju pe APM ni oun ati emewa oun yoo dibo fun fun gomina, ti awon yoo si se ti Buhari ninu ibi aare.
Lanaa, o mu alaga APM lo ba Buhari ni Abuja, nibi ti won ti mu akosile ipinnu won lati se ti Buhari fun Aare.
Sibesibe, eru ko sai maa ba awon APC Abuja pe konu-n-koho naa le daawon lagbo da sina to ba digba ibo.
Ni pataki, won ti gbe Buhari si aarin, ti oun naa si ni lati maa se tohun ati tibi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…