Home Orisirisi ‘ọkọ mi fe fi mi soogun owo!’
Orisirisi - December 20, 2018

‘ọkọ mi fe fi mi soogun owo!’

Mewaa sele ni ile ejo Magistrate’s Court to wa ni Mapo, Ibadan, lojo Alaaruba, nigba ti okunrin kan, Hakeem, ati iyawo re, Tawakalitu, jo tenu bo laasigbo to wa ninu igbeyawo won.
Iyawo lo gbe ejo lo sodo ijoba, tori o ni Hakeem, eni to je saafaa, fe fi oun se oogun owo.
O ni bi oun se mo ni wi pe, lasiko kan, baale oun bere sii pon on ni dandan pe ki awon ni ibalopo laaro ati lale. O ni kii se bee tele ati pe bayii ni oye se si oun lokan pe ejo lowo ninu.
Tawakalitu ni lojo kan ni oun wa ri tira kan ti Hakeem fi sibi igberi oun, eyi to wa je ko han si oun pe enu iku ni oun ti n je.
Hakeem naa se alaye fun ile ejo pe okuro ati alagbere paraku ni iyawo oun. Awon mejeeji ni awon kabamo pe awon fe ara awon.
Ni igbeyin, Adajo Ademola Odunade tu igbeyawo naa ka, tori o ni oro to ba fe mu emi lo, ile ejo kii fii sere, ati pe ko si ife laarin lokolya na mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…