Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE IYALODE AMINA ABIODUN: Olowo tabua miran pẹyinda ni Ibadan

IYALODE AMINA ABIODUN: Olowo tabua miran pẹyinda ni Ibadan

Ta ni ko mo Alhaja Amina Abiodun nilu Ibadan? Eni ti ko ba mo o, omode pninisin tabi ajoji godogba ni.
Bi e ko mo erin, e ko gbohun erin ni? Bi e ko mo osa, e ko je iyo lobe?
Bi e ba tile ni e ko mo Alhaja Amina Abiodun, e ko gbo orin Dauda Akanmu Epo Akara?
E o gbo bi Sikiru Ayinde Barrister se ki i? E ko gbo ewi pataki ti Olanrewaju Adepoju ke fun un ni – ti gbogbo won n so pe iduro Amina owo, ibere Amina owo, oro siso Amina, owo; aisoro Amina owo. Koda Epo Akara ni ito (saliva) Amiatulahi, owo ni!
Ah, abi e ko gbo bi Odolaye Aremu se ki Alhaja Amina Abiodun ni? O ni, “Won kan n pe lobinrin ni, ako ise lo n se/ Ele ti n be nidii e, t’ako ni/ Ojo to lo Eko lo mu moto bo.” Odun 1973 ni Odolaye Aremu, olori olorin dadakuada, ti ko orin naa!

Bee ni iya naa to je Iyalode ilu Ibadan fun ojo pipe se lowo to, paapaa nigba kan.
Sugbon mewaa sele lojo Sunday nigba ti obinrin naa je Olorun nipe.
Nigba ti won mo Efunsetan Aniwura si ijangbon, owo ati ipo nla ni won mo Alhaja Amina Abiodun si.
Oun naa kii se eni kan ti oba tabi ijoye kan le ti ni itikuti, boya idi niyi ti gbonmi sii, omi ko to o se maa n waye laarin oun ati awon alase kan leeko kan.
Sugbon sa o, bi Ibadan se n ranti Alhaji Arisekola Alao gege bii olowo tabua to se kisa ninu idagbasoke ilu, ti won si n ranti Alhaji Mufutau Lanihun gege bii Olowo tii fowo saanu, won yoo maa ranti Amina Abiodun naa gege bii eni to ran ilu ati opo eniyan lowo.
Odun 1971 ni Amina Abiodun ti bo sinu ajo to n seto ilu nigba to je oye Jagun Iyalode. Odun
2007 lo di Iyalode, leyin iku Iyalode Wuraola Akintola.
Idi niyi to fi je pe opolopo awon eniyan lo sedaro iya naa, to fi mo Gomina Abiola Ajimobi.
Ki Olorun te iya naa si afefe rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…