Home LÁGBO ÀRÍYÁ N ko le so pe tori gbajumo ni mi ki n maa ra aso N20,000 ni N100,000 – Tope Alabi
LÁGBO ÀRÍYÁ - November 13, 2018

N ko le so pe tori gbajumo ni mi ki n maa ra aso N20,000 ni N100,000 – Tope Alabi

Gbajugbaja akorin emi, Tope Alabi, ti so pe oun kii se okan lara awon ilumomika to maa n se sekarimi ainidii.
O ni opo awon alariya to je gbajumo ni won je tubu ile, yeri ode, to je pe igbesi aye iro ni won n gbe.
O ni apa won kii ka ohun ti won n da lopolopo igba, eyi to si maa n se akoba fun won.
Tope Alabi so ninu iforowero kan pe oun kii se ju ara oun lo.
O ni nigba miran, oun maa n wo moto igboro.
O tile ranti ojo kan ti oun fi moto oun sile, ti oun si wo moto ero BRT ti ijoba se agbekale re ni Eko.
Tope Alabi ni oun si maa n lo si oja funra oun lati ra worobo.
O ni awon oloja miran a ro pe tori oun je ilumomika, won a f eta aso ti ko ju egberun lona ogun (N20,000) ni egberun lona ogorun (N100,000) fun oun.
O ni ni toun o, oun kii na ina apa bee.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…